A maa gbeja orileede Niger, tawọn ọmọ ogun Naijiria ba dide si wọn-Biafra

Monisọla Saka

Ọkunrin gbajumọ ajijagbara orilẹ-ede Biafra kan to filu oyinbo ṣebugbe, Simon Ekpa, ti fọkan awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika bii Niger Republic, Mali ati Burkina Faso balẹ pe gbaagbaagba lawọn wa lẹyin wọn.

O ni ki wọn ma ṣe jẹ ki ihalẹ awọn ajọ olori orilẹ-ede Iwọ Oorun Afrika, ECOWAS, ba wọn lẹru, nitori awọn ologun to gbajọba lagbegbe wọn to n bi awọn yẹn ninu. O ni to ba di kanran-n-gida, to di pe wọn paṣẹ fawọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria lati lọọ doju ija kọ wọn, awọn Biafra yoo kun wọn lọwọ lati koju awọn ṣọja Naijiria.

Ọkunrin agbẹjọro to n gbe ni orilẹ-ede Finland, yii sọrọ ọhun ninu fọnran kan to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lori ẹrọ abẹyẹfo ‘Twitter’ rẹ.

O ni, “Mo kọkọ fẹẹ bẹrẹ ọrọ mi pẹlu ọrọ iyanju ati imulọkanle fawọn Aarẹ orilẹ-ede bii Mali, Burkina Faso ati Nijee.

Mo fẹẹ jẹ ki wọn mọ pe ọrọ ominira nilẹ Afrika, agaga lapa Iwọ Oorun Afrika tiwa nibi gbọdọ tẹsiwaju. A fẹ ki wọn mọ pe bii ike ni Biafra n bẹ lẹyin wọn lọjọkọjọ.

“A n ja ija ominira lori eto ọrọ aje ati ijagbara ominira patapata fawọn eeyan wa. Ohun to ba fi le mu kawọn ọmọ ogun Naijiria mori le ilẹ Niger lati lọọ kogun ja wọn, Biafra yoo duro ti wọn, yoo si kun wọn lọwọ.

Awọn ọmọ Biafra ti wọn le ni aadọrin miliọnu n jẹjẹẹ atilẹyin fun orilẹ-ede yoowu to ba fẹẹ ja ara ẹ gba lọwọ imunisin igbalode”.

Ekpa sọrọ yii, latari bawọn ajọ ECOWAS ṣe n dunkooko mọ awọn ologun ti wọn ditẹ gbajọba lorilẹ-ede Olominira Nijee, ti wọn si gbe aarẹ ti wọn dibo yan niluu naa, to wa lori ipo pamọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to lọ lọhun-un ni Aarẹ Bọla Tinubu, to tun jẹ olori ajọ ECOWAS, kọwe ranṣẹ sawọn aṣofin ilẹ yii, lati buwọ lu aba toun pẹlu awọn ojugba rẹ ni ECOWAS fẹnu ko le lori lati kogun ja Niger, ki wọn le ribi da Ijọba alagbada pada lorilẹ-ede naa.

Ṣaaju igba naa ni Aarẹ ti kọkọ sọ pe ọjọ meje pere loun fawọn ologun aditẹ-gbajọba ọhun lati fipo silẹ lọwọ ẹrọ, ki wọn si jẹ ki Aarẹ Mohamed Bazoum ti wọn dibo yan lorileede naa pada sori ipo rẹ. O ni ti wọn ko ba se bẹẹ laarin ọjọ meje toun fun wọn, ogun lawọn yoo fi ko wọn loju.

Bo si tilẹ jẹ pe oore-ọfẹ ọjọ meje ọhun ti wa sopin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, awọn aṣofin paapaa kọ lati fọwọ si i pe ki wọn ko awọn ọmọ ogun wa lọọ ja ni Niger.

Ṣugbọn nitori ti ọrọ le deede yi biri, ni Simon Ekpa ṣe ki awọn eeyan Niger laya, pe ẹyin wọn lawọn wa, Biafra yoo si kun wọn lọwọ lati ba Naijiria ja, bi wọn ba dide ogun.

 

Leave a Reply