Monisọla Saka
Ayọdele Fayọṣe ti i ṣe gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ti sọrọ lori bi Kwankwaso ati Obi ṣe le rẹburu wọn ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ, to si le di aṣeyọri PDP lasiko idibo naa lọwọ. O ṣapejuwe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ Labour Party, Peter Obi, gẹgẹ bii ewu nla tawọn gbọdọ sara fun ninu ibo ọdun 2023. O ni bii aisan jẹjẹrẹ ni Peter Obi ati Rabiu Kwankwaso ti ẹgbẹ NNPP ṣe jẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun yii, ni Fayọṣe sọrọ ọhun lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ Tẹlifiṣan Channels l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o loun ko nigbagbọ pe Obi le ri ida marundinlọgbọn ibo to le gbeeyan depo aarẹ mu, bẹẹ loun o lero pe ẹgbẹ awọn le ri ibo ni apa Iha Guusu Iwọ Oorun(South West) ati Guusu Ila Oorun (South East).
“Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mi, aṣaaju paapaa ni mo si jẹ ninu ẹgbẹ naa, ṣugbọn mo ti maa n sọ ọ tipẹ pe o ko le kogo ja, ti ootọ ọrọ ba ti koro lẹnu rẹ lati sọ. Ewu nla ta a o gbọdọ laju silẹ maa wo ni Obi jẹ fun wa. Mi o lero pe Obi le ni ida mẹẹẹdọgbọn (25%) ibo nipinlẹ mẹrinlelogun lasan. Ki i ṣe pe mo n ta ko Obi o, mo nifẹẹ rẹ, adari rere si lo jẹ.
Amọ, ka ma parọ, bii aisan jẹjẹrẹ apanirun ni Obi jẹ si PDP, ko si ani-ani nibẹ. Ẹ jẹ ki n fọ alaye mi si wẹwẹ fun yin. Ni apa Iha Guusu Iwọ Oorun wa nibi, awọn eeyan le ma fẹẹ gbọ ohun ti mo fẹẹ sọ, wọn le tun maa pariwo mi pe Fayọṣe tun de, ọmọ igba, ọmọ awo ni, amọ ootọ ibẹ ni pe, mi o ti i mọ bi PDP ṣe fẹẹ rọna lọ lapa Guusu Iwọ Oorun wa nibi. Ẹ jẹ kẹni to ba n tan wa jẹ mura si i, apa iha Ila Oorun (South East) gan-an ko daju fun PDP, apa Guusu Guusu (South South) ni tiwọn si ree, gbogbo ẹgbẹ lawọn yẹn n ba ṣe”.
Fayọṣe tẹsiwaju pe, wọn maa pin ibo Ariwa mọ ara wọn lọwọ ni, niwọn igba to si ti jẹ pe eyikeyii PDP tabi APC ko mu oludije kankan lati apa Ariwa Iwọ Oorun (North West), ati pe dide ti oludije dupo aarẹ lẹgbẹ NNPP, Rabiu Kwankwaso, tun de yii yoo tun mu ko nira fawọn lati ri ibo to pọ mu lapa Ariwa Ila Oorun (North East) ilẹ yii.
O sọrọ siwaju si i pe, “Ẹ jẹ ka waa pada sawọn ilu to ṣe koko lapa Ariwa. Lai tan ara wa jẹ, iṣẹ pọ fun wa ni Aarin Gbungbun Ariwa. Ẹgbẹ PDP ati APC ko mu oludije Kankan, yala fun ipo aarẹ tabi igbakeji rẹ lapa Ariwa Iwọ Oorun, iyẹn lawọn ipinlẹ bii Kaduna ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lapa Ariwa Ila Oorun, bii Yobe ati Borno lawọn APC ti yan awọn oludije tiwọn. Awa si fa ẹgbẹ wa lọ si Adamawa. Ṣugbọn ẹ o gbọdọ tun gbagbe pe bii arun jẹjẹrẹ tabi ewu ni Kwankwaso naa jẹ, oun naa si le ba ọrọ aje wa jẹ lapa Ariwa. Koda ti wọn ba fẹẹ ṣatilẹyin fun lapa Ariwa tẹlẹ, ki i waa ṣe bii pe ẹgbẹ PDP maa ko obitibiti ibo nibẹ nibi tọrọ de duro yii. Mi o ba sọ fun Atiku pe ko ṣe ọna bii aarin oun ati Obi ṣe maa daa. Eyi ti ko ba si dara ju ni ko wa ọna bi alaafia ṣe maa jọba laarin oun ati Wike”.
O ṣalaye pe ki ba daa ti ẹgbẹ awọn ati Atiku ba le ni asọyepọ pẹlu Peter Obi ati Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, iyẹn nikan lo sọ pe o le jẹ kawọn jawe olubori ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ.