Biliọnu mẹrinla Naira ni wọn yoo fi tun Aso Rock ṣe silẹ de Tinubu

Monisọla Saka

Ni ipalẹmọ fun ayẹyẹ eto iburawọle fun aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, eyi ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, awọn igbimọ to n ṣamojuto ile ijọba, Aso Rock, niluu Abuja, ti bẹrẹ atunṣe to yẹ ninu ile naa. Ninu aba eto iṣuna ọdun 2023 yii, owo to le ni biliọnu mejidinlaaadọjọ Naira ni wọn ṣeto fun ileeṣẹ Aarẹ, nigba ti biliọnu mẹrinla Naira wa fun ile ijọba gangan.

Lati Ọjọbọ, Tọsidee, to lọ yii, ni kurukẹrẹ ipalẹmọ naa ti gbera sọ. Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn ti bẹrẹ si i kun awọn odi to yi awọn apa kan lara ọfiisi Aarẹ lọda funfun ati awọ ewe tuntun.

Bakan naa ni wọn tun ti ko awọn aga atawọn nnkan ọṣọ inu ile mi-in wọ inu ile tawọn aṣofin agba ti n jokoo apero ni awọn apa kan ninu ile ijọba, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Ṣaaju akoko yii ni awọn alamoojuto ile ijọba ti ṣe afikun eto aabo agbegbe naa, ti wọn si tun gbe awọn nnkan di oju ọna tawọn eeyan n rin nibẹ, eyi to wa ni gbalasa tẹlẹ.

Gbogbo awọn eto atunṣe ti wọn n ṣe yii ni wọn lo jẹ apa kan iṣẹ tawọn igbimọ to n ri si eto igbagbara silẹ ijọba to wa nipo fun eyi to n wọle bọ, Presidential Transition Council, (PTC), eyi ti  Akọwe agba fun ijọba apapọ, Boss Mustapha, jẹ ọkan ninu wọn.

Lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii, nijọba apapọ ti ṣagbekalẹ awọn igbimọ ẹlẹni mejilelogun kan fun eto igbejọba silẹ ijọba to n wọle bọ.

Nigba to di inu oṣu Kẹrin, aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, tun fa awọn eeyan mẹrinla mi-in kalẹ lati darapọ mọ awọn igbimọ (PTC) yii.

Awọn igbimọ yii ni, “Gbogbo atunṣe ati ayipada ta a n ṣe yii jẹ ara awọn nnkan to yẹ ni ṣiṣe fun ijọba tuntun to n wọle bọ. Awọn mi-in ki i ṣe nnkan to mu wahala dani tabi to gba asiko rara, nitori loorekoore la n ṣe iyẹn, ṣugbọn to jẹ pe a maa n ṣe awọn nnkan mi-in bii atunkun ile lasiko tijọba mi-in ba fẹẹ ko wọle.

“O ṣe pataki lati kun gbogbo ibẹ, nitori lati bii ọdun meloo kan sẹyin, gbogbo awọn ibi ti igbo wa ninu ile ijọba yii ni awọn ọbọ ati aaya ti sọ dile, bi wọn si ṣe n rin yan fanda kiri nibẹ ni wọn n fi ara nu ogiri, eyi to n tibẹ mu ki ara ogiri dọti. Bẹẹ lawọn àdán naa ko gbẹyin, gbogbo igbẹ wọn ni wọn ti fi ba ara ogiri jẹ tan”.

Nigba to n sọrọ siwaju lori iye ti wọn na lori iṣẹ atunṣe naa, o ni, “A ko tayọ iye eto iṣuna ta a ti la kalẹ, ṣugbọn awọn igbimọ PTC, ni wọn n ṣenawo awọn nnkan mi-in to ba ṣe pataki to yọju lojiji”.

Lọjọ Ẹti,  Furaidee, ọjọ Karun-un, oṣu Karun-un, ọdun yii, kan naa, ni Oluranlọwọ pataki si Aarẹ lori eto iroyin, Garba Shehu, gba ori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ lọ, nibẹ lo gbe fọto ọkunrin kan to n kun ara ogiri ayika ile ijọba ni awọ ewe ati funfun si. O waa kọ ọ si abẹ aworan naa pe, “Awọn kunlekunle ree lẹnu iṣẹ wọn. Atunṣe ile ijọba n lọ lọwọ fun aarẹ tuntun to n wọle bọ”.

Wọn ni atunṣe naa ṣe pataki nitori ọṣẹ tawọn kokoro, ekute atawọn ẹranko wẹwẹ mi-in ti ṣe fun awọn ẹrọ amuletutu, aga atawọn nnkan mi-in to wa ninu ile ijọba ni gbogbo asiko ti aarẹ Muhammadu Buhari lọ fun isinmi ọlọjọ gbọọrọ ko kere. Yoo si na wọn to biliọnu mẹrinla Naira lati mu ile naa pada bọ sipo gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Leave a Reply