Bimbọ Ademoye tu aṣiri nla: Mama mi lẹni akọkọ to ja mi kulẹ ju lọ laye

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni b’ọdẹ ba ro iṣẹ, ro iya, bo ba pẹran, ko ni i fẹnikan jẹ. Ọrọ yii lo ṣe wẹku pẹlu ọpọ ipenija ati airọgbọ ti pupọ ninu awọn oṣere ilẹ wa n mu mọra, ti wọn si n la kọja labẹnu. Loootọ ni wọn maa n fara han ninu awọn sinima ati lori tẹlifiṣan, tabi lori ẹrọ ayelujara bii ẹni pe gbogbo nnkan n lọ fun wọn daadaa, amọ o fẹrẹ jẹ pe koowa wọn lo ni ibi ti bata ti n ta a lẹsẹ, ọpọ wọn lo si ni awọn nnkan to jẹ ipenija fun wọn.

Iru rẹ ni ti oṣere-binrin apọnbeporẹ to rẹwa bii ọkin nni, Bimbọ Ademoye. Ọpọ igba lo jẹ pe baba gbajumọ oṣere yii lawọn eeyan mọ, oun si ni wọn maa n ri pẹlu rẹ ju lọ. Koda nigba to gba ami-ẹyẹ kan ni African Magic laipẹ yii, ọdọ baba rẹ lo kọkọ gbe ẹbun pataki naa lọ, ti wọn si jọ dawọọ idunnu.

Ṣugbọn ọpọ eeyan ni ko mọ pe oṣere to kopa to jọju ninu fiimu Anikulapo yii ṣi ni mama laye, koda ibi ti mama rẹ n gbe si ile rẹ ko ju irin ogun iṣẹju pere lọ.

Ki lo waa fa a ti ajọṣe oun ati baba rẹ fi ṣe timọtimọ ju ti mama rẹ lọ? Bimbọ Ademoye tu aṣiri kan tawọn eeyan ko mọ tẹlẹ, arẹwa oṣere yii ni ọmọọdun meji pere loun wa ti mama oun fi ja oun ju silẹ, to si ba tirẹ lọ lai wẹyin, lai bikita.

Laipẹ yii, iyẹn lasiko to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu oniroyin kan, Hauwa Magaji, lo dahun ibeere ti wọn bi i nipa iya rẹ ọhun. Ibẹ ni Bimbọ Ademoye ti ṣalaye pe:

“Mi o ki i fẹ sọrọ kan mama mi, tori mo maa n fẹ kawọn eeyan bọwọ fun ipinnu ti mo ṣe nipa rẹ. Ọmọọdun meji pere ni mo wa ti mama naa ti ja mi ju silẹ lọ.

Maami ṣi wa, wọn wa laye, wọn wa laaye, koda ibi ti wọn n gbe ko fi bẹẹ ju bii irin ogun iṣẹju si ibi temi n gbe lọ. Amọ emi o ki i ṣe alapẹpẹ to bẹẹ, mi o ki i sọrọ pupọ.

“Ẹni akọkọ to ja mi kulẹ nigbesi aye mi ni maami. A ti gbiyanju lati ṣẹ ewe le ọrọ naa lori, amọ ṣe oju apa le jọ oju ara ṣa, tori ko fi bẹẹ si ifẹ atọkanwa kan laarin wa, tori mi o gbọnju mọ wọn rara.

Amọ mo gbiyanju lati ni ajọṣe pẹlu wọn, sibẹ naa, ko jọra wọn. Ni bayii, a ti jọ n ṣe pọ diẹdiẹ. Mo n ṣe ojuṣe mi gẹgẹ bii ọmọ si wọn, mo n san owo ile ti wọn n gbe mo si n fun wọn lawọn owo ajẹmọnu kan. Ko ju bẹẹ lọ o, o si tẹ mi lọrun bẹẹ. Mi o fẹ ki ajọṣe naa sun mọra ju bẹẹ lọ, mi o si ba wọn dọrẹẹ kan bii alara, tori mi o fẹ nnkan to maa ko ironu ba ọpọlọ mi, tabi to maa ṣakoba fun ilera mi.”

O fi kun un pe: “Mama mi wa daadaa, obinrin to dudu, to rẹwa, to si lomi lara daadaa ni. Baba mi ni mo fi bi mo ṣe pupa jọ, tori awọn mọra daadaa, amọ bi mo ṣe ri mugbẹ-mugbẹ yii, ọdọ maami ni mo ti riyẹn.”

Bimbọ lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply