Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹṣẹ n paayan loootọ, to ba ba ni nibi to lagbara. Iru awọn ẹṣẹ buruku bẹẹ lo jọ pe Biọdun Adebiyi, ẹni ọdun mejilelọgbọn ( 32), fi pa ọmọkunrin kan, Mukaila Adamu, ẹni ọgbọn ọdun (30), lagbegbe Ajegunlẹ, n’Idiroko, nitori ṣenji aadọta Naira lasan to fẹẹ gba lọwọ ọkunrin naa.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu kejila yii, niṣẹlẹ naa waye. DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ṣalaye pe Baba Mukaila to ku lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan Idiroko, pe ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Sannde naa ni Biọdun waa ra siga lọwọ ọmọ oun, Mukaila, bo si ti ra a tan lo ba tiẹ lọ.
Baba Mukaila tẹsiwaju pe afi bo ṣe di nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Sannde naa ti Biọdun tun de, to ni oun fẹẹ gba ṣenji fifti naira lọwọ ọmọ oun.
Ọrọ ṣenji wazo naa lo dija laarin wọn bi baba yii ṣe wi, lo ba di pe Biọdun bẹrẹ si i lu ọmọ oun bii ko ku, to n ku u lẹṣẹẹ gidi. Awọn ẹṣẹ agbara naa lo jẹ ki Mukaila ṣubu lulẹ, ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan, nibi tawọn dokita ti sọ fun wọn pe o ti ku.
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun mu Biọdun to n gbe l’Ojule karundinlogoji, Opopona Ọladun, Ikọtun, nipinlẹ Eko, Idiroko to ti lọọ daran naa ni wọn ti mu un, bẹẹ ni wọn ti gbe oku Mukaila lọ si mọṣuari, wọn ni wọn yoo ṣe ayẹwo fun un.
Wọn ti gbe Biọdun funra ẹ lọ sẹka ti wọn ti n ri si ọrọ awọn apaayan, nibi ti wọn yoo ti towe rẹ lọ sile-ẹjọ