Jide Alabi
Bi ijọba ipinlẹ Eko ba mu ileri rẹ ṣẹ, a jẹ pe oṣu keji, ọdun to n bọ, ni wọn yoo ṣi oju ọna Agege-Pen Cinema ti wọn ti n kọ lati aye ijọba Akinwumi Ambọde.
Sanwoolu lo sọ eleyii di mimọ ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lasiko to ṣabewo si biriiji oni kilomita meji din diẹ (1.7km) yii.
Akọwe iroyin gomina, Gboyega Akọsile, sọ lorukọ rẹ pe iṣẹ ti fẹrẹ pari lori ọna Agege-Pen-Cinema, ida aadọrin iṣẹ naa lo si ti jẹ ṣiṣe bayii.
Gomina ni gbogbo iṣẹ to jẹ mọ biriki lawọn ti ṣe tan, nnkan meji to kan ku ni lati ri i pe awọn oju ọna naa mọ toni toni, ati fifi ami atọka si i, eyi to ni awọn yoo ṣe nibẹrẹ ọdun to n bọ.
Bẹẹ nijọba ti fun awọn agbaṣẹṣe naa ni ọsẹ mẹfa pere lati ṣe gbogbo awọn atunṣe to ba yẹ lori iṣẹ oju ọna naa.
Sanwoolu ni igbesẹ yii waye lati mu ileri ti awọn ṣe pe gbogbo iṣẹ ti ijọba ana n ṣe lọwọ ko too kuro nipo lawọn yoo pari ṣẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ijọba Akinwumi Ambọde lo bẹrẹ biriiji naa. Ireti rẹ ni lati pari rẹ ni saa ẹlẹẹkeji rẹ ko too di pe wọn ko fun un ni tikẹẹti lati dije dupo lorukọ ẹgbẹ APC l’Ekoo.