Jọkẹ Amọri
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ki ọmọ jayejaye, to ti sọ ara rẹ di obinrin pẹlu imura ati isọrọsi ẹ nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, tabi Mummy of Lagos, ma pada sọgba ẹwọn o. Nibi tọrọ naa si buru de, bi wọn ba tọwọ iwadii bọ ọ, ọmọkunrin yii nikan kọ ni yoo pada sọgba ẹwọn, yoo tun mu awọn alagbara orileede yii kan lọwọ, nitori o ti fọrọ ẹnu rẹ ko ba wọn, o ti fi ẹjọ buruku de okun mọ wọn lẹsẹ, boya ni wọn yoo si bọ ninu ọran ti Bobrisky ko wọn si yii.
Fọnran kan lo lu sita, ọmọkunrin kan to maa n sọrọ lori ayelujara ti wọn n pe ni Very Dark Man lo gbe itakurọsọ to waye laarin Bobrisky ati ọkunrin kan ti wọn lo filuu Amẹrika ṣebugbe to jẹ ọrẹ Bobrisky, torukọ rẹ n jẹ Kayọde Jacobs.
Lasiko ti wọn mu Bobrisky fun ẹsun pe o ṣe owo ilẹ wa baṣubaṣu ati pe o n ṣe agbodegba lati gbe owo lọ silẹ okeere fun awọn kan, eyi ti wọn n pe ni money lundaring, ni wọn ni o bẹbẹ awọn oṣiṣẹ EFCC, pe ki wọn yọ ẹjọ money lundering yii kuro lara ẹsun oun. N lawọn yẹn ba ni ko lọọ mu miliọnu mẹẹẹdogun Naira wa. Owo ọhun lo n wa to fi pe ọkunrin to fi orileede Amẹrika ṣebugbe naa pe ko ya oun ni miliọnu mẹrin.
Nigba to n ṣalaye ohun to feẹ fi owo naa ṣe lo sọ pe oun ko fẹẹ duro sinu ọgba ẹwọn, ati pe baba alaye oun ti ba oun pe ọga agba ọgba ẹwọn lorileede wa, wọn si ti ba oun ṣeto ile kan to sun mọ ọgba ẹwọn, ṣugbọn miliọnu mẹwaa Naira ni wọn yoo gba lọwọ oun fun eleyii, oun ko si le lo asunwọn akaunti oun lati fi owo naa ranṣẹ si wọn.
Ohun ti o tumọ si ni pe Bobrisky ko sun oorun ọjọ kan ninu ọgba ẹwọn Ikoyi, bẹẹ ni EFCC ti ran an lọwọ lati yọ ẹsun pe o n ba awọn eeyan ṣe agbodegba owo to lodi sofin lọ silẹ okeere atawọn ibomi-in, eyi lo fi jẹ pe ẹsun pe o n ṣe owo ilẹ wa baṣubaṣu ni wọn tori ẹ ju u sẹwọn oṣu mẹfa. Gbogbo eeyan lo si sọ nigba to jade lẹwọn loootọ pe niṣe ni oju rẹ n dan, ti awọn rẹ si tutu, ko si jọ ẹni to lọ sọgba ẹwọn rara.
Bẹẹ lo darukọ agbẹjọro pataki kan nilẹ wa ati ọmọ rẹ, pe awọn ni wọn fẹẹ ba oun ṣeto bi oun ṣe le beere fun idariji, ti orukọ rẹ yoo fi kuro ninu awọn to ti ṣẹwọn ri.
Ohun ti Bobrisky tabi Mummy of Lagos, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe e ko mọ ni pe gbogbo ohun to n sọ ni ọmọkunrin naa ti k
Lẹyin ti Bobrisky jade lọgba ẹwọn, eyi ti iba fi da owo ọkunrin ara Amẹrika to ya a lowo pada, niṣe lo kọ ti ko sanwo naa, to si tun n halẹ mọ ọn. Gbogbo ikilọ ti tọhun si n sọ pe oun maa tu aṣiri rẹ jade, o ro pe o n halẹ lasan ni. Eyi lo mu ki Kayọde Jacobs fi itakurọsọ to waye laarin ohun ati ọmọ jayejaye Eko naa ranṣẹ si ọkunrin ti wọn n pe ni VDM yii, niyẹn ba gbe e sita.
Nibi tọrọ naa si le de, ALAROYE gbọ pe ọga awọn EFCC ti paṣẹ pe ki iwadii to rinlẹ waye lori awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọọṣẹ rẹ.
Yoruba ni ta a ba fa gburu, gburu yoo fa igbo. Gburu ti Bobrisky fa yii ti n fa ọpọlọpọ nnkan bayii, bẹẹ lo si ti n ṣakoba fun awọn kan. Pẹlu bi nnkan si ṣe ri yii, afaimọ ki Idris Okunnẹyẹ ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky ma pada sọgba ẹwọn, ki i ṣe pe yoo pada sibẹ nikan kọ bayii, yoo gbe aṣọ ọgba ẹwọn naa wọ, ti yoo si jokoo laarin awọn ọdaran, iyẹn bi gbogbo ẹsun ti wọn kan si i lẹsẹ ọhun ba jẹ tootọ.
ALAROYE gbọ pe lati wẹ ara rẹ mọ kuro ninu wahala naa, Bobrisky ti sare sanwo to jẹ ọmọkunrin naa. Bẹẹ lo ti tun gbe ọrọ jade pe ki awọn araalu ma da awọn to gbe itakurọsọ kan jade, ti wọn ni oun loun sọ ọ, o ni ohun oun kọ lo wa nibẹ, wọn parọ mọ oun ni.
Ṣe Bobrisky yoo bọ ninu wahala naa bayii, ko sẹni to ti i le sọ.