Monisọla Saka
Ọkunrin gbajumọ ori ẹrọ ayelujara to n pe ara ẹ lobinrin, to si maa n mura bii obinrin, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, ti tun gbọna mi-in yọ lati fi da awọn eeyan loju pe obinrin loun, gbogbo nnkan to ba gba loun yoo si fun un lati maa da gọjọgọjọ, koun si maa jidi bii obinrin nigba gbogbo.
Lati le jẹ kawọn eeyan mọ pe oun ti ṣiṣẹ abẹ ti wọn fi n yi ọkunrin pada si obinrin, lọdun to kọja lo bu ẹnu atẹ lu ọkunrin kan to ja ọrẹbinrin ẹ silẹ lojiji. Nigba to n sọ si ọrọ naa, Bobrisky ni, “Awọn ọkunrin o ni ṣalai ma doju ti ẹ. Awọn eeyan radarada kan, Ọlọrun ṣeun temi o ki i ṣe ara wọn mọ”.
Lojuna ati le bu kun ẹwa ẹ ni Bobrisky ṣe tun lọọ ṣiṣẹ abẹ ti yoo mu ki idi ẹ tobi daadaa ju bo ṣe wa lọ.
Lopin ọsẹ to kọja yii, lo gbe fidio ibi to ti n ṣiṣẹ abẹ naa sori ẹrọ ayelujara ti wọn maa n fi ya fọto (Snapchat), fawọn eeyan lati ri i pe loootọ ni nnkan toun n sọ.
Bakan naa lo tun gba oju opo ayelujara Facebook rẹ lọ lati sọ fawọn eeyan pe iṣẹ abẹ toun lọ fun ki i se eyi to rọrun, irora nla lo wa ninu ẹ, ṣugbọn to ba jẹ lori ka ṣe oge, kinu oun si dun ni, oun ti ṣetan lati mu irora naa mọra, lati le ṣe ohun ti o wu oun.
“Irora iṣẹ abẹ o le dena idunnu mi, ẹru irora yẹn n ba mi loootọ, amọ mi o ni i yee ṣiṣẹ lori ati le rẹwa si i”.
Bo tilẹ jẹ pe ko too ṣe iṣẹ abẹ to ṣẹṣẹ ṣe yii, ati bi gbogbo imura rẹ ṣe jẹ ti obinrin, awọn eeyan ko nigbagbọ pe nnkan ọmọkunrin ẹ ti yipada si tobinrin.
Nitori eyi, ọpọ igba lo ti fi itara sọrọ lori bi wọn o ṣe nigbagbọ, ti wọn o si fara mọ keeyan yipada lati ọkunrin si obinrin tabi lati obinrin si ọkunrin nilẹ Naijiria.
Lati le jẹ ki wọn mọ pe oun ko mu un ni kekere lo fi tun lọọ ṣe iṣẹ abẹ tuntun yii, to si tun gbe fidio sita kawọn eeyan le ri i.
Ninu fidio ọhun ni obinrin kan ti daya delẹ pẹlu idi to han pe wọn ṣẹṣẹ ṣiṣẹ abẹ lori ẹ, pẹlu oriṣiiriṣii nnkan ti wọn di mọ ọn janganjangan lo wa nibẹ.
Bobrisky kọ ọ sabẹ fidio naa pe, “Mo ti ṣe idi tuntun mi-in, mo n gbadura ki gbogbo oju egbo yẹn tete jinna tan kia”.
Yẹyẹ lawọn eeyan n fi Bobrisky ṣe lori ayelujara, wọn ni o kan n tan ara ẹ jẹ ni, nitori ara obinrin tawọn n wo ninu fidio ki i ṣe ti Bobrisky, wọn ni gbogbo nnkan to ba wu u ni ko dan wo, titi dọla lawọn mọ pe ki i ṣe obinrin.