Bobrisky ti sọrọ o: Eyi nidi ti mo ṣe sa lọ siluu oyinbo 

Adewale Adeoye

Gbajumọ ọmọ jayejaye to nifẹẹ lati maa mura bii obinrin nni, Idris Okunẹyẹ, ẹni tawọn eeyan mọ si Bobrisky, ti sọ idi pataki to ṣe tete yẹra kuro lorileede Naijiria, to si lọọ farapamọ siluu oyinbo bayii.

Ọmọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Mummy of Lagos yii ni inu oun ko dun rara si bawọn agbefọba orileede yii ṣe n fọwọ lile mu ọrọ oun, paapaa ju lọ lori awọn ẹsun t’oun ko mọ nnkan kan nipa rẹ ti wọn fi kan oun.

Atẹjade kan to fi sita lori ẹrọ ayelujara rẹ lo ti sọ pe, ‘‘Mo bọ mọ wọn lọwọ o, mo ti kuro lorileede Naijiria fun igba diẹ na, ma a le raaye ṣetọju ara mi daadaa, ma a si tun jẹ igbadun aye mi daadaa nibi ti mo wa bayii. O ṣe pataki pupọ fun mi lati lọọ ṣetọju ara mi. Mi o ki i ṣe onidọti eeyan, ma a too pada sorileede Naijiria, nibi ti wọn ti bi mi, ṣugbọn mo kọkọ gbọdọ lọọ ṣetọju ara mi na. Awọn agbofinro orileede Naijiria kan fẹẹ yọ ile aye lẹmi-in mi, ṣugbọn Ọlọrun Ọba ko gba fun wọn.

Bẹ o ba gbagbe, ẹẹmeji ọtọọtọ ni Bobrisky ti kọkọ gbiyanju lati kuro lorileede Naijiria lati lọọ s’Oke-Okun, ṣugbọn tawọn agbofinro orileede yii fọwọ ofin mu un. Akọkọ ni igba too fẹẹ gba ẹnuubode Seme kọja lọ si orileede Bẹnnẹ, tawọn kọsitọọmu orileede wa da a duro, ti wọn di mu un. Igba keji ni eyi tawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC tun wọ ọ bọ silẹ lati inu ọkọ baaluu KLM kan ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport, l’Ekoo, lasiko to fẹẹ lọ si London, wọn lo lẹjọ lati jẹ lọdọ awọn. O si lo to ọjọ meji lọdọ wọn, ti wọn fi n fọrọ wa a lẹnu wo nipa ẹsun pe o fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ EFCC kan ni abẹtẹlẹ, ki wọn le ba din ẹsun ti wọn fi kan an ku. Ṣugbọn Mummy of Lagos loun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan oun, lẹyin ti ajọ EFCC ṣewadii rẹ daadaa ni wọn da a silẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu yii, pe ko maa lọ.

Bobrisky ko fọrọ naa falẹ rara, niṣe lo ko ẹru rẹ, lo ba gba ilu oyinbo lọ. Inu baaluu lo si ti n sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn maa kira foun, nitori ẹẹmẹta loun sanwo aaye akọkọ ninu baaluu, eyi to ni o to miliọnu lọna ọgbọn Naira.

Ni bayii, ọmọkunrin jayejaye naa ni oun lọọ fara nisinmi ni o, oun ko sa lọ.

 

Leave a Reply