Faith Adebọla
Bi gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, ba fi Oriyọmi kun orukọ rẹ lasiko yii, o to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ, pẹlu bi Ọlọrun ṣe ko o yọ lọwọ iku ojiji to ka a mọ, nigba tawọn eeṣin-o-kọ’ku ẹda kan ti wọn fura pe ikọ mujẹ-mujẹ Boko Haram ni wọn lọọ lugọ de gomina yii ninu ikọ akọwọọrin rẹ nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii, wọn pa ọlọpaa meji ninu awọn ẹṣọ alaabo rẹ, awọn ọlọpaa mẹfa mi-in si farapa yanna-yanna.
ALAROYE gbọ pe ibi ayẹyẹ igboye-jade awọn akẹkọọ Fasiti Maiduguri, iyẹn University of Maiduguri, nibi ti wọn ti lọọ fi oye dokita ( Ọmọwe) da Igbakeji Aarẹ orileede yii, Kashim Shettima lọla, ni gomina yii ati awọn ikọ rẹ lọ, amọ nigba ti wọn n ṣẹri bọ, awọn Boko Haram naa ti lọọ lugọ de e, lai mọ pe gomina yii ko ba ikọ akọwọọrin rẹ ọhun pada, kidaa awọn ẹṣọ alaabo lo wa ninu awọn ọkọ ọlọla ati tọlọpaa to gbemu tẹle ara wọn naa.
Ilu Maiduguri ti wọn lọ naa ni gomina duro si, tori o fẹẹ ba ọna ibomi-in re kọja lọ siluu Abuja, fun nnkan mi-in.
Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Yobe lori eto iroyin, Mamman Mohammed, lasiko to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin sọ pe, “bi ikọ akọwọọrin gomina yii ṣe n gba ọna Jakana si Mainok pada bọ wa siluu Damaturu, niṣe ni wọn ko sọwọ awọn agbebọn ti wọn ti gẹgun de wọn yii, ti wọn si bẹrẹ si i ṣina ibọn bolẹ, awọn ọlọpaa naa si dana ibọn ya wọn gidi, mẹta ninu awọn ọlọpaa yii lo fara gbọgbẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Ọkan ninu awọn agbofinro to wa nibi iṣẹlẹ yii, amọ ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ, sọ pe Gomina Buni gan-an lawọn afẹmiṣofo naa dọdẹ rẹ wa, wọn tun gbiyanju boya wọn le ri ja gba ninu awọn ọkọ akọtami, iyẹn Mine Resistant Ambush Protected Vehicles (MRAP) to maa n tẹle awọn gomina.
Amọ awọn ẹṣọ alaabo naa ko kẹrẹ, wọn rọjo ibọn lu wọn gidi, ọpọ ninu awọn afẹmiṣofo yii lo fara kona ibọn, eyi lo si mu ki wọn sa lọ nigba to ya.
Lẹyin ti eruku ija naa rọlẹ lawọn agbofinro tẹsiwaju irin-ajo wọn, ti wọn si tete gbe awọn ọlọpaa to fara gbọta lọ sileewosan ijọba to wa nitosi fun itọju pajawiri.
Amọ owuyẹ kan fidi ẹ mulẹ pe ko din ni ọlọpaa meji to ku. Wọn ni ọkan ku loju-ẹsẹ, nigba ti ọkan tun dagbere faye lasiko ti wọn n ko wọn lọ sọsibitu.