Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Tọpẹ Ọlọmọla, ẹni ogun ọdun, ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo ti ju sẹwọn bayii lori ẹsun pe o la irin nla (sledge hammer) mọ ọmọbinrin kan to n sanwo fun awọn eeyan (POS Attendant) lori lasiko to fẹẹ jale ni ṣọọbu rẹ.
Agbefọba, Inspẹkitọ Ọlayiwọla Rasaq, ṣalaye fun kootu pe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun yii, ni olujẹjọ huwa naa ni Agbajọwọ Community, Akede, lagbegbe Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo.
O ni ṣe lo fẹẹ ji owo Bọlanle Rainat, to si la oolu naa mọ ọn lori, eleyii to nijiya labẹ ipin irinwo o le mẹta (403) ati ọtalelọọọdunrun o din marun-un (355) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Bi wọn ṣe ka ẹsun naa si Tọpẹ leti lo sọ pe oun jẹbi wọn. Nitori idi eyi, Adajọ Abayọmi Ajala sọ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, tigbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.
Ajala ni ki agbefọba mu ẹda iwe ẹsun olujẹjọ lọ si ẹka to n ri si igbẹjọ araalu (DPP), nipinlẹ Ọṣun, fun imọran.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nita kootu, Bọlanle ṣalaye pe oun tun n ta ọti ẹlẹridodo pẹlu ẹrọ ipọwo toun n ṣe. O ni ṣe ni Tọpẹ de pẹlu ọkada rẹ lọsan-an ọjọ naa, to si ni oun fẹẹ ra Coke, ati pe oun fẹẹ mu un koun too kuro ninu ṣọọbu naa.
O ni nigba to n mu kooki ọhun lọwọ lo deede dide lẹẹkan naa, to si yọ oolu nla naa jade lara ọkada rẹ nigba to ri i pe ko sẹnikankan layiika. O ni ṣe lo pakuuru mọ oun, to si la irin naa mọ oun lori.
Bọlanle ni, “Ariwo ti mo pa ni ko jẹ ko duro ko owo mọ, lo ba n sa lọ, lemi naa ba n sare tẹle e pẹlu ẹjẹ lori mi, bayii lawọn eeyan ba mi le e titi ti wọn fi ri i mu, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ”