Buba ti dero ẹwọn o, wọn lo wa kusa lọna aitọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Arakunrin awakọ tirela, ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Buba Mohammed, ni Adajọ A. Sanni, ti sọ sẹwọn ọdun kan bayii fẹsun pe o lọọ wa kusa lọna aitọ lagbegbe Lade, nijọba ibilẹ Pategi, nipinlẹ Kwara.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ yii, EFCC, lo wọ afurasi ọdaran naa lọ si ile-ẹjọ fẹsun pe o lọọ wakusa lọna aitọ, o si fẹẹ lọọ ta awọn nnkan alumọọni ilẹ wa to wa jade ọhun lawọn ipinlẹ mi-in.

Nigba ti wọn ka awọn ẹsun rẹ si i leti ni kootu, Buba gba pe loootọ loun ti rufin, oun si jẹbi.

Ṣe bẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, wọn ni ki i pẹ lori ikunlẹ, bi Buba ṣe rawọ ẹbẹ ni kootu naa l’Adajọ Sanni gbe idajọ rẹ kalẹ pe ko lọọ ṣẹwọn ọdun kan, pẹlu iṣẹ aṣekara, tabi ko san ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (#400,000) gẹgẹ bii owo itanran, ki gbogbo ẹru ofin ti wọn ba lọwọ rẹ si di tijọba apapọ.

Wọn ni ti ko ba rowo itanran san, tabi to jẹ ẹwọn lo wu u iṣe, ki wọn bẹrẹ si i ka irinajo ẹwọn rẹ fun un lati lati ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, tọwọ ti tẹ ẹ.

Adajọ ni eyi yoo kọ awọn ọdaran bii tiẹ lọgbọn.

Leave a Reply