Monisọla Saka
Gbajumọ elere fuji nilẹ yii, Alaaji Wasiu Ayinde Marshal, ti pupọ eeyan mọ si K1 de Ultimate tabi ọba Fuji, nijọba Buhari ti fẹẹ fun ni ami-ẹyẹ MON, ọkan lara awọn eeyan pataki nilẹ yii, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii.
Akitiyan atawọn ipa pataki tọkunrin olorin yii ti ko ninu idagbasoke ilẹ yii latẹyinwa titi di isinyii, lo mu ki ipo ati ami-ẹyẹ idanilọla naa tọ si i.
Gẹgẹ bi iroyin to jade lati ileeṣẹ to n ri si awọn iṣẹ pataki atawọn eto ijọba lọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun yii ṣe sọ, wọn ni ninu gbọngan International Conference Center, to wa l’Abuja, layẹyẹ igbami-ẹyẹ naa ti maa waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni deede aago mẹsan-an owurọ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, Minisita fawọn iṣẹ pataki ni, “Mo layọ lati fi to yin leti pe Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọlọla ju lọ Muhammadu Buhari, ti buwọ lu iwe lati ṣapọnle yin pẹlu oye ati ami-ẹyẹ lati jẹ ọkan lara awọn eeyan pataki nilẹ yii (MON).
‘‘Ni gbọngan International Conference Centre, ICC, to wa niluu Abuja, layẹyẹ naa ti maa waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii, ni deede aago mẹsan-an aarọ.
‘‘Aaye ilegbee, to fi mọ jijẹ mimu, la ti ṣeto silẹ fun yin nile itura Nicon Hotel. Iforukọsilẹ ati iwọle sileetura yii yoo bẹrẹ laago mejila ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii. Kaadi idanimọ yin ṣe pataki fun iwọle atawọn eto yooku.
O ki gbogbo wọn ku oriire ami-ẹyẹ ati ipo nla ti wọn fi da wọn lọla naa, o si ṣe e laduura pe wọn yoo rẹmii lo o.