Buhari fi ami-ẹyẹ da awọn eeyan to le ni irinwo lọla

Adewumi Adegoke

Gbogbo awọn lookọ lookọ, awọn eeyan jankan jankan niluu, oniṣẹ ọwọ, oloṣelu ati ọba alaye ni wọn wa ninu awọn eeyan ti wọn le ni irinwo ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi ami-ẹyẹ lọkan-o-jọkan da lọla niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwa, ọdun 2022 yii.

Gbọngan International Conference Centre, to wa niluu Abuja, ni ayẹyẹ pataki yii ti waye.

Lara awọn ọba alaye ti wọn fun lami-ẹyẹ ni Ọọni Ileefẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, ti wọn foye Commander of The Federal Republic (CFR), da lọla lori ipa takun takun to n ko lori ọrọ awọn ọdọ, to si tun jẹ ẹni to n wa alaafia kaakiri ilẹ wa ati ilẹ adulawọn lapapọ.

Awọn mi-in ni Ọba ilu Benin, awọn gomina, awọn olokoowo atawọn oṣere.

Leave a Reply