Buhari fi ami-ẹyẹ da Jonathan, Wike atawọn eeyan mi-in lọla

Monisọla Saka

Gbọngan nla Conference Centre, to wa nile ijọba, niluu Abuja, ni Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari,  ti fami-ẹyẹ da Aarẹ ilẹ yii tẹlẹ, Goodluck Ebele Jonathan, atawọn eeyan mẹtalelogoji mi-in lọla fun awọn iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe fun itẹsiwaju orilẹ-ede yii.

Ami-ẹyẹ ti wọn n pe ni NEAPS yii, ni wọn n fun awọn eeyan lati fi ẹmi imoore iṣẹ ribiribi ti wọn gbe ṣe han, yala ti wọn ti ṣe fun ẹyọ eeyan kan, fun ilu, ipinlẹ tabi odidi ilu ati orilẹ-ede lapapọ gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba, tabi adari to n ṣiṣẹ sin ilu ati ọmọniyan.

Iru awọn tiru ami-ẹyẹ yii tọ si gbọdọ jẹ ẹni to ti ṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba tabi iṣẹ adani, to ṣi wa lorilẹ alaaye, ṣugbọn to ti kopa pataki kan tabi omi-in ninu ilọsiwaju orilẹ-ede yii kọja ibi ti iṣẹ wọn mọ lati ri i daju pe awọn ko ipa ribiribi lati tun awujọ ṣe, ko si tun goke agba.

Bakan naa ni wọn yoo tun fi ami-ẹyẹ yẹ awọn gomina nipinlẹ mẹrindinlogun nilẹ yii si, titi kan Ahmed Lawan, ti i ṣe Olori ileegbimọ aṣofin agba, Fẹmi Gbajabiamila, to jẹ Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin atawọn eeyan jankan jankan mi-in nileeṣẹ ijọba fun ipa ribiribi ti wọn ko ninu idagbasoke orilẹ-ede yii.

Lara awọn gomina ti wọn fi ami-ẹyẹ da lọla ni gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, Gomina Yahya Bello ti ipinlẹ Kogi, Atiku Bagudu ti i ṣe gomina ipinlẹ Kebbi, Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun, Dave Umahi ti Ebonyi, Babagana Zulum ni Borno, ati Bala Muhammed ti ipinlẹ Bauchi. Awọn Minisita ti wọn n ṣejọba pẹlu Aarẹ Buhari ti wọn yoo tun fi ami-ẹyẹ ṣapọnle wọn ni ọga agba ajọ NNPC, Mele Kyari, Mohammed Nami ti i ṣe ọga patapata ileeṣẹ to n gba owo ori lorilẹ-ede yii, FIRS, naa wa nibi ayẹyẹ ọhun.

Leave a Reply