Monisọla Saka
Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari, iyawo ẹ, Aishat Buhari atawọn mọlẹbi wọn, ti tu jade lati dibo yan adari tuntun ti yoo tukọ orilẹ-ede yii fun ọdun mẹrin mi-in. Nibudo idibo kẹta, 003, Sarkin Yara A, agbegbe Kofar Baru, Daura, nipinlẹ Katsina, loun pẹlu awọn eeyan ẹ ti tẹka. Aago mẹwaa aarọ ku iṣẹju mẹta ni Aarẹ atiyawo ẹ de ibudo idibo, pẹlu ogunlọgọ ero ti wọn n wọ tẹle wọn lẹyin, ti wọn si n ṣe sadankata wọn.
Ni kiakia to de ibudo idibo ẹ ni wọn ti ṣe ayẹwo orukọ fun un, o si dibo ẹ ni kete tawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, INEC ti ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ṣiṣe fun un.
Ohun ti ẹnikẹni ko lero pe o le ṣẹlẹ rara ni Aarẹ Buhari ṣe, ko too ju beba to tẹka si sinu ike ti wọn gbe sibẹ, niṣe lo na beba naa soke fawọn eeyan lati ri nigba ti wọn duro le e lọrun pe ko fi han awọn, tayọtayọ lo si fi na an soke fun wọn lati ri.
O waa rọ awọn ọmọ Naijiria ati gbogbo awọn oludije funpo aarẹ pata lati gba esi idibo ti wọn ba kede, ati gbogbo ẹni yoowu to ba jawe olubori gẹgẹ bii ayanfẹ awọn araalu. O ni ki wọn gbaruku ti iru ẹni bẹẹ, fun anfaani ati itẹsiwaju orilẹ-ede wa.