Buhari pariwo: Awon to n waa ba mi fun iranlọwọ lo jẹ ki n sa lọ siluu oyinbo-Buhari

Adewale Adeoye

Olori orileede Naijiria tẹlẹ, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti sọ idi to ṣe sa kuro ni Naijiria, to sa gba oke okun lọ lati lọọ fun ara rẹ nisinmi.

Ọkunrin naa ni oun mọ-ọn-mọ sa gba ilu London lọ ni lati lọọ fun ara oun nisinmi daadaa, nitori bawọn eeyan ko ṣ yee da giri-giri wa sile oun niluu Daura, nipinlẹ Katsina, lati waa ba oun fun iranlọwọ ohun kan tabi omiran.

Buhari ni afi bii ọja ni awọn eeyan ṣe n ya wa sile oun nigba gbogbo, ti wọn si n beere fun oniruuru iranlọwọ kan tabi omiiran, leyii ti apa oun paapaa ko ka rara, nigba ti ki i ṣe pe oun loun ṣi wa nipo aarẹ orile-ede yii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro eto iroyin Buhari, Ọgbẹni Garba Shehu fi sita laipẹ yii lo ti sọ pe, ‘Gbara ti Buhari ti pari iṣakoso rẹ niluu Abuja, lo ti pinnu lati pada siluu rẹ ti i ṣe Daura, lati maa lọọ gbe igbe alaafia nibẹ, ṣugbọn nigba tawọn eeyan, paapaa ju lọ, awọn oloṣẹlu kọọkan ti wọn fẹ ki Buhari ran awọn lọwọ lati ri ipo pataki di mu ninu ijọba to wa lode yii ko yee da giri-giri waa ba a nigba gbogbo lo ṣe kuku sa gbalu oyinbo lọ lati lọọ fun ara rẹ nisinmi ọlọjọ diẹ.

‘‘Oun lo mọ ohun to fẹ lati ṣe, ipinnu rẹ si ni pe ilu oyinbo, nibi ti ko ti ni i sẹnikankan lati di i lọwọ lo ti fẹẹ lo isinmi rẹ bayii. O ṣe pataki gan-an fun un lati fun ara rẹ nisinmi ko too pada wa silẹ Naijiria bayii. Paapaa ju lọ bi Buhari ṣe ti filu silẹ yii yoo le jẹ ki olori orile-ede Naijiria tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, gbajumọ iṣakoso ijọba rẹ daadaa, ko si le mu ileri gbogbo to ṣe fawọn araalu lakooko ipolongo ibo ṣẹ fun wọn pata’’.

Bẹ ọ ba gbagbe, aipẹ yii ni Buhari gba oke okun lọ lati lọọ fun ara rẹ nisinmi ọlọjọ diẹ, eyi to sọ pe ọ ṣe pataki gidi foun nitori pe awọn eeyan ko yee da wa sile rẹ to wa niluu Daura, nipinlẹ, Katsina, fun iranlọwọ.

Oke-okun ti Buhari wa yii lo ti tun ṣepade pajawiri kan pẹlu Aarẹ Tinubu lakooko tawọn mejeeji pade, ṣugbọn ti ko sẹni to mọ ohun ti ipade ọhun da le lori.

Leave a Reply