Lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari tun lọ si ilu abinibi rẹ, Daura, nipinlẹ Katsina. Abẹwo idakọnkọ ọlọjọ mẹrin ni wọn lo lọọ ṣe nibẹ.
Bẹ o ba gbagbe, Aarẹ ilẹ wa lọ fun iru irinajo yii kan naa ninu oṣu kejila ọdun to kọja. Lasiko naa ni wọn ji awọn ọmọ ileewe girama to jẹ ti ijọba to wa ni Katsina gbe, ko too di pe wọn pada fi wọn silẹ.