Faith Adebọla
Lọtẹ yii, awọn aṣofin apapọ ti koro oju si ibeere ijọba apapọ pe ki wọn fọwọ si ẹyawo igba miliọnu naira ti wọn lawọn fẹẹ fi ra awọn apẹfọn, iyẹn nẹẹti tawọn eeyan yoo maa sun sabẹ rẹ lati dena arun iba.
Ibeere ijọba apapọ yii wa lara ohun ti wọn kọ sinu eto iṣuna owo ti wọn lawọn fẹẹ na lọdun 2022, eyi ti ileegbimọ aṣofin mejeeji ilẹ wa l’Abuja n ṣiṣẹ le lori lọwọ.
Igbimọ alabẹ ṣekele awọn aṣofin agba lori ọrọ abelẹ ati tokeere to n tuṣu deṣalẹ ikoko awọn ibeere fun ẹyawo ọlọkan-o-jọkan lo fajuro si ẹyawo igba miliọnu dọla ($200m) ti ileeṣẹ eto ilera ijọba apapọ (Federal Ministry of Health) lawọn fẹẹ ya ọhun, wọn ni awọn apẹfọn fun ipinlẹ mẹtala ti arun iba (malaria) ti n ja ranyin ju lọ nilẹ wa lawọn fẹẹ tori ẹ ya a.
Akọwe agba ileeṣẹ eto ilera naa, Ọgbẹni Mahmuda Mamman, ṣalaye fawọn aṣofin ọhun pe “ti ileegbimọ aṣofin ba fọwọ si ẹyawo yii, ta a si ri owo naa gba, a maa fi gbogun ti arun iba lawọn ipinlẹ mẹtala ti ko loluranlọwọ, ijọba ibilẹ igba ati mẹjọ (208) lo wa lawọn ipinlẹ yii, ẹgbẹrun mẹta aabọ (3,536) ileewosan alabọọde ijọba (Primary Health Care Centres) lo si wa nibẹ.”
Alaye to ṣe yii ko dun mọ awọn aṣofin naa rara, wọn si fariga fun Mamman ati akọwe rẹ, Dokita Faisal Shuaib. Sẹnetọ Ibrahim Oloriẹgbẹ atawọn sẹnetọ yooku nijokoo naa ni wọn beere pe bawo ni ileeṣẹ naa ṣe ti kọkọ beere ojilenirinwo ati mẹwaa miliọnu naira (N450m) lati koju iṣoro arun iba, ti wọn si tun fẹẹ yawo rẹpẹtẹ yii lori ọrọ arun iba yii kan naa, ninu aba eto iṣuna 2022 yii kan naa.
Oloriẹgbẹ ni, “eyi o bojumu rara, a o le gba a. A gbọdọ le duro lori ẹsẹ wa gbọ-in ni pẹlu awọn ibeere ẹyawo wọnyi ati ohun ti wọn fẹẹ tori ẹ yawo.
Ṣe ko sawọn to le ṣe nẹẹti apẹfọn lorileede wa ni? Ṣe ko si awọn egboogi arun iba nibi ta a le fi ẹyawo ọhun ra ni, ka tiẹ la a fọwọ si i?
Niṣe lawọn ileeṣẹ to n wa ẹni ti wọn fẹẹ ya lowo kan fẹẹ maa di ẹbiti gbese ru awọn ti ko ba dakan mọ, ti wọn aa tun maa sọ ibi ti tọhun le nawo le lori fun un. Ẹ sọ fun Washington abi ki lẹ ti pe awọn ti wọn fẹẹ ya wa lowo ọhun pe ki wọn yee fọwọ ọtun ya wa lowo, ki wọn si maa fọwọ osi gba a pada lọwọ wa o, a o fẹ’ru ẹ.
Ọrọ to jọra pẹlu eyi ni Sẹnetọ Adelere Oriolowo lati ipinlẹ Ọṣun ati Sẹnetọ Abba Moro lati ipinlẹ Benue, atawọn to ku naa sọ.