Awọn aṣofin ilẹ wa ti sọ pe ki Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, jade, ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori rogbodiyan to n lọ kaakiri lori bi awọn ọdọ ṣe n fi ẹhonu han ta ko gbogbo iwa aburu tawọn SARS n hu nilẹ yii.
Bakan naa ni wọn ni ki awọn ọlọpaa pese aabo to peye fun awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han naa ki awọn janduku ma baa ja iwọde naa gba mọ wọn lọwọ.
Bẹẹ ni wọn rọ Aarẹ lati gbe igbimọ oluwadii ti awọn ọdọ yoo nigbagbọ ninu rẹ kelẹ lati ṣewari awọn SARS ti wọn n huwa ibi yii, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn.
Wọn waa rọ awọn ọdọ naa lati kuro ni oju titi, ki ijọba le dahun si awọn ibeere wọn.