Jọkẹ Amọri
Lati ri i pe adinku ba iye awọn oludije, ati lati ṣipẹ fun awọn kan ninu awọn to fẹẹ dije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Aarẹ Buhari ṣepade pẹlu awọn oludije naa nile ijọba niluu Abuja, ni alẹ ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa yii.
Titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii ni ipade naa n lọ lọwọ, ko ti i sẹni to mọ ibi ti wọn yoo fẹnu rẹ ko si.
Bẹ o ba gbagbe, awọn gomina APC to wa lati iha Ariwa ti fẹnu ko, bẹẹ ni wọn ti rọ awọn eeyan wọn to fẹẹ dije lati jawọ ninu rẹ, ki wọn si fun awọn eeyan Guusu ni anfaani lati fa oludije kalẹ ti yoo kopa ninu ibo abẹle wọn ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ.