Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan Ọga agba ṣọja, Frouk Yahaya gẹgẹ bii ọga ologun ilẹ wa tuntun.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni ileeṣẹ Aarẹ kede ọkunrin naa.
Ki wọn too yan sipo tuntun yii, ohun ni ọga ologun patapata ẹka ologun to n ri si gbigbogun ti awọn afẹmiṣofo ni Ila Oorun-Ariwa.
Ọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni, ọdun 1966 ni wọn bi i siluu Sifawa, nijọba ibilẹ Bodinga, nipinlẹ Sokoto.
O kawe nileeṣẹ awọn ologun, bẹẹ lo ti di awọn ipo pataki pataki mu loriṣiiriṣii