Jọkẹ Amọri
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣiṣọ loju eegun owo ilẹ wa ti wọn ṣẹṣẹ pa awọ rẹ loju da. Ọga agba banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria, Godwin Emefiele, lo sọ eleyii di mimọ fawọn oniroyin lẹyin ipade ti awọn alẹnulọrọ lori ọrọ owo ilẹ wa, iyẹn (Monetary Policy Committee) ṣe.
O ni ni deede aago mẹwaa aarọ ni eto ṣiṣi aṣọ loju owo tuntun naa yoo waye lasiko ipade awọn igbimọ apaṣẹ ilẹ wa.
O waa dupẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari fun atilẹyin to n ṣe fun ẹka ijọba naa. Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn aṣọfin ati ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), fun akitiyan wọn, eyi to mu ki eto naa rọrun fun awọn.
Bakan naa ni Emefiele ni awọn ko ni i fi kun ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ to jẹ gbedeke ti awọn fun awọn eeyan lati paarọ owo wọn.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ọga agba banki ilẹ wa kede pe awọn fẹẹ fun awọn owo ilẹ wa ni awọ tuntun, nitori bi wọn ṣe dọti, ati lati fopin si bo ṣe jẹ pe ita ni ọpọlọpọ owo ilẹ wa to yẹ ko wa ni banki wa. Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila yii ni wọn yoo ko owo na jade bii ọmọ tuntun.