Monisọla Saka
Aṣofin to ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ Kaduna nileegbimọ aṣofin niluu Abuja tẹlẹ, Sẹnetọ Shehu Sani, ti sọ pe bukaata nla ni awọn gomina tẹlẹri ti Aarẹ Tinubu fi ṣe minisita ninu ijọba rẹ.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni ọkunrin naa kọ ọrọ yìí soju opo ayelujara Twitter rẹ, lati le fi bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti Tinubu gbe ọhun.
O ni, “Awọn to mọ iṣẹ wọn niṣẹ, to si jẹ pe aaye to jẹ mọ iṣẹ wọn ni wọn fun wọn nipo si ninu ijọba Tinubu ni a le ri bii nnkan-ini tabi ọrọ̀ ilu, ṣugbọn ṣẹ ẹ ri awọn gomina tẹlẹri to wa nibẹ, bukaata ati gbese nla lawọn yẹn duro fun”.
Tẹ o ba gbagbe, awọn gomina tẹlẹ bii mẹsan-an, ti awọn mẹta ninu wọn jẹ gomina to ti jẹ ri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ alatako, PDP, ni Tinubu fi ṣọwọ sawọn aṣofin pe wọn yoo di ipo minisita mu ninu ijọba oun. Ọrọ yii ko ba ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lara mu nitori ati ipo kan bọ si ipo mi-in lo jẹ fawọn gomina tẹlẹri ọhun.
Ọrọ yii lo bi Shehu Sani ninu to fi gba ori ẹrọ ayelujara lọ pe igbesẹ to le fa ijọba rẹ sẹyin ni Tinubu gbe pẹlu awọn gomina tẹlẹri ọhun to mu mọra.
Lara awọn gomina ẹgbẹ PDP to wa ninu awọn ti yoo ba a ṣejọba papọ ni Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers tẹlẹ, ati olori awọn gomina ẹgbẹ PDP marun-un tinu n bi, Dave Umahi, ti i ṣe gomina ipinlẹ Ebonyi, atawọn gomina mi-in bẹẹ.