Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọmọ ti ku iya o gbọ nile. Iyẹn lọrọ ọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan torukọ ẹ n jẹ Alexander Uzoma, l’Abẹokuta. Ẹni to fẹsẹ ara ẹ rin jade nile lọọ ba awọn ọmọ Yahoo to n ba ṣọrẹ to riku he nibẹ, tawọn iyẹn gbe oku ẹ sọnu sori biriiji ni Kutọ, tijọba si pada sin oku ẹ bii alailẹni kan!
Iya Uzoma, Ogechi Alexander, ko mọ pe ọmọ oun ko ni i pada wale nigba tọmọ naa jade kuro nile logunjọ, oṣu kọkanla, to kọja yii, to ni oun fẹẹ de ọdọ awọn ọrẹ oun kan, afi bi ọmọ ṣe lọ ti ko wale lọjọ naa.
Nigba ti iya rẹ ko ri i lo lọọ sọrọ naa fun wọn ni teṣan ọlọpaa Adigbẹ, l’Abẹokuta. Awọn ọlọpaa kede rẹ bii ẹni to sọnu, wọn lawọn n wa Uzoma Alexander, ẹni ogun ọdun.
Ṣugbọn lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ti kede yii ti wọn ko gburoo kankan, CP Lanre Bankọle ti i ṣẹ ọga ọlọpaa Ogun, paṣẹ pe ki wọn gbe faili ọmọ naa lọ sẹka ti wọn ti n ṣewadii ati itọpinpin iwa ọdaran.
Nigba naa lawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ yii, wọn si pada ri i pe ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Babatunde Owoṣeni lẹni naa ti wọn ri pẹlu Uzoma gbẹyin, ni wọn ba mu un.
Mimu ti wọn mu Babatunde lo ṣatọna bi wọn ṣe mu Azeez Oyebanji ti wọn n pe ni Biggy, wọn mu Ayọbami Adeṣina ati Balogun Sulaiman pẹlu.
Nigba tawọn ọlọpaa fọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn ọkunrin mẹrin yii jẹwọ pe Uzoma wa sile awọn lati kọ nipa bi wọn ṣe n ṣe yahoo, iyẹn jibiti ori ayelujara.
Wọn ni lẹyin tawọn jẹun tan, awọn mu oogun oloro amara-gba-yagiyagi ti wọn n pe ni ‘Colorado’. Wọn ni kinni naa jẹ ki gbogbo awọn sun lọ fọnfọn ni.
Wọn tẹsiwaju pe o to nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa kawọn too ji, bawọn si ti ji lawọn ri Uzoma to ṣi wa nidubulẹ ni tiẹ, to si ti bi si gbogbo ara.
Awọn ọmọkunrin yii ṣalaye pe nigba tawọn gbiyanju lati gbe e dide lawọn ri i pe ko mi mọ, o ti ku patapata.
Nigba ti wọn ko mọ ohun ti wọn yoo ṣe si oku naa, wọn ni Biggy lawọn pe, nitori oun lo ta Colorado tawọn mu fawọn, n ni Biggy ba ni ko buru, ṣiṣe tun ku, lo ba fawọn yooku nimọran pe ki wọn jẹ kawọn ju oku Uzoma nu jare.
Bayii ni Ayọbami ati Sulaimọn ṣe ṣeto fun awakọ Uber pe kan ko wa, biyẹn ṣe de ni Ayọbami gba mọto lọwọ rẹ, o si fi gbe oku Uzoma lọ sori afara Kutọ, nibẹ lo ju u si to ba tiẹ lọ.
Gẹgẹ bi atẹjade DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ yii sita si ṣe wi, awọn oṣiṣẹ eleto ilera ijọba ipinlẹ Ogun lo palẹ oku naa mọ gẹgẹ bii iṣẹ ti wọn, iyẹn nigba ti wọn ri i lẹyin tawọn to ju u nu ti ba tiwọn lọ.
Ki wọn too palẹ oku naa mọ lati sin in gẹgẹ bii oku ijọba ti ko leeyan, awọn oṣiṣẹ eleto aabo yii ya fọto oku naa, wọn si ri apa kan nibi ori rẹ, eyi to fi han pe ipalara wa fun oku ọhun ki wọn too pa a, o han pe awọn kan ti fi nnkan ṣe e ko too dagbere faye.
Aṣẹ ti wa pe ki iwadii ṣi tẹsiwaju lori iku Uzoma yii, bo si tilẹ jẹ pe wọn yoo gbe awọn ọrẹ rẹ mẹrin yii lọ si kootu laipẹ, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn gende mẹrin yii lo lo Uzoma.
Wọn ni nigba to jẹ yahoo asiko yii ti kuro ni ki wọn ṣe gbaju-ẹ foyinbo lasan, to ti n mu ẹmi eeyan dani, to jẹ wọn n tẹ ẹ nidii nilana awọn agba ni, bi wọn ṣe n lo obinrin naa ni wọn n lo ọkunrin.
Nigba ti Uzoma ko si si laye mọ lati ṣalaye ohun to pa a, iwadii iku rẹ lo ku tawọn ọlọpaa gbaju mọ, iya rẹ nikan lo si ku to n ṣọfọ gende ọmọ.