Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ E.O Idowu, tile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Isabo, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ni wọn foju Ọgbẹni Kọlajọ Damilare ba. Ẹsun iwa ọdaran ti awọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi ‘Nigeria Security And Civil Defence Corps’ (NSCDC), ẹka tipinlẹ naa fi kan an ni pe o lọọ ji ẹru ile bii ẹrọ amule-tutu, (Refridgerator), ẹrọ to n gbana sara (Stabilisers) ati ina to wa lẹgbẹẹ ile, Security-Light, to jẹ ti Ọgbẹni Razaq Salaudeen, to n gbe laduugbo Bode Olude, l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.
ALAROYE gbo pe awọn ara agbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni wọn sare pe ajọ NSCDC kan ti wọn n lọ kaakiri agbegbe naa, pe ki wọn waa mu Damilare sọdọ ko too di pe awọn to n lu u fibinu pa a danu lori ohun to ṣe.
Loju-ẹsẹ tawọn oṣiṣẹ ajọ ọhun debi ti wọn ti n lu Damilare ni wọn ti gba a silẹ, ti wọn si mu un lọ sọdọ wọn, ibẹ lo ti jẹwọ pe loootọ loun jalẹkun Ọgbẹni Salaudeen wọle, toun si ji awọn ẹru inu ile rẹ kan gbe sa lọ ko too di pe ọwọ tẹ oun.
Ọga agba ajọ ọhun, Ọgbẹni David Ọjẹlabi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin pe awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun, ẹka ti Opeji, ni wọn n lọ kaakiri aarin ilu, ti wọn si gba Damilare silẹ lọwọ awọn to mu un fun iwa ọdaran to hu.
‘‘Ẹsun iwa ọdaran kan ṣoṣo la fi kan Damilare, ẹsun ọhun naa ni pe o jalẹkun ile onile lẹyin rẹ, to si ji awọn dukia rẹ gbe sa lọ.
Nigba to maa sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, Damilare rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ ọhun pe ko ṣiju aanu wo oun.
Adajọ ile-ẹjọ ọhun, Onidaajọ E.O Idowu, ni ki Damilare lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ asekara tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150, 000) gẹgẹ bii owo itanran.