Dada Ajikanje
Lati le dẹkun iru ijamba ina to waye niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Gomina ipinlẹ naa, Dapo Abiọdun ti ni ijọba ko ni i gba awọn dẹrẹba to ba gbe tanka epo laaye lati maa kọja lori awọn biriiji kaakiri ipinlẹ naa. Owo itanran to lagbara lo ni yoo wa fun awọn ti wọn ba kọti ikun si ofin yii lati ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun.
Igbesẹ yii ko ṣeyin ina buruku kan to jo nigba ti tanka kan sọ ijanu rẹ nu laaarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii nitosi banki GTB to wa ni Abẹokuta.
Lori ikanni Instagraamu rẹ ni Abiọdun ti sọrọ naa lẹyin to ṣabẹwo sibi tiṣẹlẹ naa ti waye.
Gomina ni, ‘‘Nigba ti mo ṣe agbeyẹwo iṣẹlẹ naa, alaye ti wọn ṣe fun mi ni pe ijanu ọkọ epo naa ni ko mu un mọ ti ijamba naa fi waye, to si fi lọọ kọ lu awọn ọkọ kan, eyi to fa akọlukọgba, bi ki i baa si ṣe pe awọn tọrọ kan tete dide si i ni, iba buru ju bayii lọ.
‘‘Awọn dokita akọṣẹmọṣẹ nipa awọn ti wọn ba ni ijamba ina la ranṣẹ si lati ipinlẹ Eko pe ki wọn waa tọju awọn ti ina jo ninu iṣẹlẹ naa. Gbogbo awọn to ni ijamba ti mo ṣabẹwo si ni ọsibitu ijọba to wa ni Ijaye, ati ọsibitu ijọba apapọ to wa ni Idi-Aba, la maa san owo itọju wọn.
‘‘Bakan naa ni mo ba awọn mọlẹbi awọn eeyan mẹfa to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa kẹdun.’’
Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni ijamba ina naa ṣẹlẹ, nibi ti eeyan mẹfa ti ku, ti ọpọ mọtọ si jona gburu gburu.