Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lati mu inu awọn olukọ dun nipinlẹ Ogun, ki wọn si tun le jara mọṣẹ wọn si i, Gomina Dapọ Abiọdun da awọn to fakọ yọ ninu awọn tiṣa naa lọla layaajọ ọjọ awọn olukọ ti ọdun yii, ile ati miliọnu owo lo fun wọn.
Nibi eto naa to waye ni Oba’s Complex, l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, lọjọ karun-un, oṣu kẹwaa yii, ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Gomina Abiọdun fun Ọgbẹni Kẹhinde Ọladapọ ti i ṣe tiṣa nileewe Japara Junior Secondary School, n’Ijẹbu-Igbo, ni ile oniyara meji.
Esteeti ijọba to wa ni Kọbapẹ ni ile ọhun wa, wọn fun Ọgbẹni Ọladapọ nitori oun lo gba ipo olukọ to dara ju lọ nipinlẹ Ogun lẹka naa.
Yatọ si ile yii, Ọgbẹni Ọladapọ tun gba ẹbun owo miliọnu meji aabọ (2.5m) fun jijẹ olukọ to peregede ju lọ ni gbogbo ipinlẹ Ogun.
Bakan naa ni tiṣa kan, Ọgbẹni Uche Bakare, lati ileewe Army Day Secondary School, Owode Yewa, gba ẹbun olukọ to dara ju nileewe girama agba nipinlẹ Ogun. Miliọnu meji naira ni gomina fun un gẹgẹ bii ẹbun imọriri.
Ni ẹka ileewe alakọọbẹrẹ, Oluwadare Odutayọ to jẹ olukọ nileewe All Saints African Primary School, Ijẹbu-Igbo, lo peregede ju, Gomina Dapọ Abiọdun si foun naa ni miliọnu meji naira owo ṣiṣe daadaa.
Gomina ṣalaye pe igbesẹ yii ṣe pataki, nitori ẹ kuuṣe lo n mu ori ẹni to ba n ṣiṣẹ ya, yoo jẹ iwuri fun wọn lati ṣe si i, yoo si jẹ kawọn yooku naa mura si iṣẹ wọn.
Ṣaaju ni Alaga awọn olukọ nipinlẹ Ogun (NUT), Ọgbẹni Abiọdun Akinọla, ẹni ti Akọwe ẹgbẹ, Ọgbẹni Samson Oyelere, ṣoju fun ti bẹ gomina pe ko tete san owo kọpuretiifu ti wọn n yọ lara awọn tiṣa loṣooṣu lai san an pada fun wọn.
O ni ai sanwo yii n ko ba aye ọpọlọpọ tiṣa nipinlẹ Ogun, ṣiṣẹ wọn si ti fẹẹ maa da bii ọlẹ.