Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Kokoro to n jẹ igba, idi igba lo wa. Iyẹn ni ti oṣiṣẹ banki kan, Ọlagoke Dare, ẹni to gbimọ-pọ pẹlu Idowu Tunde, pe ki iyẹn dibọn bii ole, ko si waa gba miliọnu mẹta naira ti banki ran oun lọọ gba, ko maa gbe e lọ, kawọn si pada jọ pin in.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa yii, niṣẹlẹ naa waye.
Banki kereje ti wọn n pe ni Microfinance kan ni Dare n ba ṣiṣẹ l’Abẹokuta. Banki naa lo ran oun ati ọmọbinrin kan, Mary Agbejo, ti wọn jọ n ṣiṣẹ ni banki ọhun pe ki wọn lọọ gba miliọnu mẹta naira wa nileefowopamọ kan l’Oke-Ilewo.
Aṣe Dare ti ba ọkunrin to n jẹ Tunde Idowu yii di i pe ko waa da awọn lọna, ko si gba owo naa lọ. Ọmọbinrin ti wọn jọ lọ si banki ko si mọ nnkan kan ni tiẹ.
Bi wọn ṣe gba owo ọhun tan ti wọn wọnu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe lọ si banki pada, Tunde to ti sa pamọ sẹyin ọkọ naa (Dare mọ-ọn-mọ pa ilẹkun ọkọ naa de lai ti i ni, ki ẹni to fẹẹ gba owo lọwọ wọn le raaye ko wọnu ẹ) fa ayederu ibọn kan yọ, lo ba na an si Mary, ọmọbinrin to gbe tiri miliọnu naa dani.
Ṣugbọn ọmọbinrin naa ṣe ọkan akin, o ri i pe ibọn ti ọkunrin yii n na si oun ko jọ ibọn tootọ, ayederu kan bayii ni. N lọmọbinrin yii ba lọ ibọn naa mọ ọn lọwọ, bẹẹ lo n pariwo ole, to n pe kawọn eeyan gba awọn o.
Awọn to wa nitosi da si ohun to n ṣẹlẹ naa, wọn si mu adigunjale alayederuba ibọn naa, ni wọn ba fa a le ọlọpaa lọwọ.
Nigba ti ọwọ iya ba Tunde to fẹẹ fibọn onirọba gbowo naa, o jẹwọ fawọn ọlọpaa pe Dare, oṣiṣẹ banki lo ni koun waa da awọn lọna, oun naa lo si foun nibọn awuruju pe koun fi dẹru bawọn kiṣẹ le ṣe.
Ṣa, Adele ọlọpaa agba nipinlẹ Ogun, DCP Abiọdun Alamutu, ti ni ki wọn ko Dare ati Tunde yii lọ sẹka SCID, nibi ti iwadii yoo ti tẹsiwaju.
O rọ awọn agbanisiṣẹ pe ki wọn ri i daju pe wọn mọ awọn eeyan ti wọn fẹẹ gba siṣẹ deledele, nitori iru awọn eeyan bii Dare Ọlagoke yii ti wọn jẹ amọniṣeni.