Jamiu Abayọmi
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, David, ti wa lakolo awọn agbofinro latari bo ṣe gun Aafaa Akeem Ojiwusi pa, lẹyin to fa oogun oloro yo tan lagbegbe Abule-Ẹgba, nipinlẹ Eko.
ALAROYE gbọ pe o ti mọ David lara, o si ti di iwa rẹ lati maa mumu imukumu bii ọti lile, siga, igbo, ati kolorado, ti awọn nnkan wọnyi ṣi maa n jẹ ko ṣiwa-hu, eyi to maa n mu ko fa wahala laduugbo to ba ti yo tan.
Ṣefiu to jẹ ọkan lara mọlẹbi oloogbe yii ṣalaye pe, “Lọjọ Aiku, Sannde, ni aafaa pe oun lati lọọ ba oun ra oogun wa fun aisan kan to n ṣe wọn, ṣugbọn oun ko ti i rin jinna toun fi n gbọ ti oloogbe naa n pariwo, ‘ẹ gba mi! Ẹ gbami! ninu ile, ti mo si sare pada. O ya mi lẹnu lati ri David to ti n gun aafaa lorikerike ara, tori o ti yo lasiko ta a n sọ yii”.
ALAROYE gbọ pe ni kete ti David gun aafaa ti ko sẹni to ti i mọ ohun to ṣẹlẹ laarin oun ati David to fi gbe igbesẹ naa ni aafaa bẹrẹ si i bẹ awọn eeyan to wa nitosi pe ki wọn ran oun lọwọ, ki wọn ma jẹ ki oun ku bayii, to si n pariwo, Allah! Allah! Oju-ẹsẹ ni wọn ni Iya to bi David to gun aafaa pa yii atawọn araadugbo ti gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn nigba ti wọn fi maa debẹ, ọkunrin naa ti jade laye, tori o ti padanu ẹjẹ pupọ.
Bi awọn mọlẹbi David ṣe gbọ pe aafaa ti ku ni wọn ti sa lọ. Koda, foonu oloogbe yii wa lọwọ iya afurasi ọdaran yii di bi a ti n sọ yii, ti ko si sẹni to mọ ibi ti obinrin naa wa di akoko yii, bo tilẹ jẹ pe oun lo lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa to wa ni Oko Ọba.
Awọn ti wọn mọ ọmọkunrin yii sọ pe o maa n mu oriṣiiriṣii nnkan to maa n yi i lori, ti yoo si maa ṣe bii were kiri adugbo. Wọn ni David yii ti fẹẹ fipa ba aburo rẹ laṣepọ ri, ọpẹlọpẹ awọn araadugbo ti wọn gbọ ariwo ọmọbinrin yii ti wọn fi gba a silẹ.
ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ sileewosan ijọba to wa ni Ikẹja, niluu Eko.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hudeyin, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin pe lọjọ Aiku, Sannde ni wọn fiṣẹlẹ naa to awọn leti nipa iṣẹlẹ naa, wọn si ti gbe David lọ si ẹka to n ri si iwa ọdaran ni Panti. O ni lẹyin iwadii lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.