Ọlawale Ajao, Ibadan
Aṣe loootọ lowe awọn agba to sọ pe ori yeye ni mogun, taiṣẹ lo pọ. Aimọye eeyan lọmọ araye ti pa nitori iwa ọdaran ti wọn o mọwọ mẹsẹ nipa rẹ.
Ninu owe Yoruba mi-in ẹwẹ, awọn agba bọ, wọn ni oloootọ ki i ku sipo ika. Owe yii gan-an lo ba ọrọ baba ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Ọgbẹni Tọpẹ Aluko, mu pẹlu bi awọn eeyan ṣe mu un ni imu ọdaran, ti wọn si mura lati ko taya bọ ọ lọrun ki wọn le dana sun un.
Lagbegbe Baṣọrun, n’Ibadan, niṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii nigba ti awọn eeyan mu Ọgbẹni Tọpẹ Aluko fun ẹsun ijinigbe.
Lẹyin ti wọn ti ṣa baba naa ladaa, ti wọn si ti lu u ni kumọ bii ewurẹ to jale nisọ onigaari, ni wọn pinnu lati dana sun un, wọn ni gbọmọgbọmọ ni i ṣe, ati pe iṣu to wa ninu baagi to gbe lọwọ ki i ṣe iṣu lasan, awọn ọmọọleewe meji kan ti wọn n lọ si sukuu jẹẹjẹẹ wọn lo fi oogun lu ti wọn fi yipada di iṣu naa.
Awọn ọlọpaa to tete de sibẹ l’Ọlọrun fi yọ ọ ti ko jẹ ki wọn ri i pa.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, baba ti ori ko yọ lọwọ iku oro yii ṣalaye pe, “Agbalagba ni mama to ran mi niṣu pe ki n lọọ ba awọn gbe e fun ọmọ awọn ni Sango. Mi o si le kọṣẹ fẹni to ju mi lọ, ati pe inu ile kan naa la jọ n gbe.
“Aago mẹfa idaji ti kọja nigba yẹn. Nigba ti mo debi ti mo ti maa ṣi geeti wọle ni wọn bi mi pe nibo ni mo n gbe iṣu ọwọ mi lọ, pe ki n tu u wo. Mo ni bi wọn ṣe gbe e fun mi lemi n gbe e lọ yẹn. Wọn ni ki n ṣaa tu iṣu ọwọ mi silẹ.
“Ki n too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn mẹrin ti ṣuru bo mi pẹlu ada ati ibọn lọwọ wọn. wọn ni o ya, ki n da iṣu yẹn silẹ, mo ni ki wọn ṣi geeti fun mi ki n kọja kiakia nitori mo n lọ sibi iṣẹ. Wọn ni wo bo ṣe n ba wa sọrọ. Bi ọkan ninu wọn ṣe la mi ladaa lẹyin niyẹn. O fi ada lu mi lẹẹkinni, o fi lu mi lẹẹkeji. Mo kan ṣubu lulẹ ni.
“Bi wọn ṣe de mi lokun lọwọ sẹyin niyẹn. Ọkan ninu wọn l’Ọlọrun fọwọ tọ lọkan to lọọ sọ fẹni to gba mi siṣẹ pe wọn ti fẹẹ pa mi o. Nigba ti Alaaji de, wọn o dawọ duro naa, wọn ṣáà n ko ada bo mi ni. Igba tawọn ọlọpaa de ni wọn too gba mi silẹ.
“Awọn ọlọpaa beere lọwọ mi pe ki lo ṣẹlẹ, mo ṣalaye fun wọn pe Alaaja lo ran mi pe ki n lọọ ba awọn gbe iṣu fọmọ awọn ni Sango, nitosi ibi ti mo ti n ṣiṣẹ. Awọn eeyan waa fẹẹ pa mi, wọn ni eeyan ni mo sọ di iṣu. Mo ni iṣu ree lọwọ mi, nibo ni wọn ti reeyan? Pe ki iṣu deeyan, mi o gbọ iru ẹ ri lati ọjọ ti mo ti daye.
“Ni gbogbo asiko yẹn, awọn eeyan ti pọ gan-an ti wọn pe le mi lori. Ẹnikan gbe tasin Micra silẹ pe ki n wọnu ẹ ki wọn ma baa dana sun mi.”
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mukẹ, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, sọ pe ẹsun ti awọn eeyan mu lọ si teṣan ni pe ẹnikan sọ awọn ọmọọleewe meji di iṣu. Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa agbegbe yẹn ti bẹrẹ iwadii, ti wọn si ri i pe ko si nnkan to jọ ọ.
“DPO agbegbe yẹn tun waa lọ sileewe ti wọn sọ pe awọn ọmọ ti wọn sọ di iṣu n lọ. Wọn beere pe njẹ akẹkọọ kankan sọnu nileewe yẹn, ṣugbọn ọga ileewe sọ pe ko si obi to mu ẹsun wa pe oun n wa ọmọ oun.
“Ọga ileewe yẹn tun paṣẹ pe ki wọn lu aago pajawiri lati pe gbogbo awọn akẹkọọ jọ. Funra DPO ati ọga ileewe yẹn ni wọn ka gbogbo ọmọọleewe yẹn lọkọọkan, ti wọn si ri i pe wọn pe perepere.
CP Onadeko waa rọ gbogbo ara ipinlẹ naa lati ṣọra fun idajọ atọwọda. O ni niṣe ni ki wọn fa ẹnikẹni ti wọn ba fura si pe o huwa ọdaran le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii ati ijiya to ba tọ siru ẹni bẹẹ ni ibamu pẹlu ilana ofin.