Jọkẹ Amọri
Gbogbo awọn to gbọ ifọrọwerọ kan ti ọkan ninu awọn oṣere ile wa, Kẹmi Afọlabi, ṣe pẹlu oniroyin kan, Chude Jideonwo lo ti ṣalaye pe oun ni aisan kan ti wọn n pe ni Lupus. Aisan yii lo maa n da orikerike ara, ẹdọ, kindinrin ọpọlọ atawọn ẹya ara mi-in laamu. Niṣe ni yoo maa rẹ ẹni to ba ni aisan naa, gbogbo orike ara yoo maa ro o, iba yoo maa ṣe e, bẹẹ laọn nnkan le maa su si i lara.
Ohun to buru nibẹ ni pe aisan yii ko ṣe e wo, Ẹni to ni i yoo maa loogun si i ni titi ti ọlọjọ yoo fi de.
Kẹmi Afọlabi to n ṣalaye fun akọroyin naa pẹlu omije loju sọ pe nigba ti oun lọ sọdọ dokita ni dokita ni ọdun marun-un loun ni lati lo laye, oun si ti lo ọdun kan nibẹ bayii, oun ko si ti i mọ iye to ku foun lati lo.
Oṣere yii ni dokita yii sọ pe, ‘‘Ri i pe o yi ara rẹ ka pẹlu awọn to nifẹẹ rẹ, o ṣi ni bii ọdun marun-un si i lati lo laye.
Kẹmi ni aisan naa ko ṣe e wo, eeyan yoo kan maa tọju rẹ ti yoo si maa loogun titi aye ni. O ni miliọnu kan ati igba Naira (1.2) loun ti na laipẹ yii fun itọju aisan naa, ṣugbọn pẹlu ẹ naa, inu inira ni oun maa n wa nigba gbogbo.
Oṣere yii fi kun un pe oun ti kọ iwe ipigun oun, oun si ti ra posi ti wọn yoo fi sin oun silẹ bi oun ba ku.
Gbogbo awọn ti wọn gbọrọ naa ni wọn ti n gbadura fun oṣere yii pe ko si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe, Ọlọrun yoo mu un larada.