Jọkẹ Amọri
Iyawo Igbakeji Aarẹ orileede yii, Dọlapọ Ọṣinbajo, ti ki ọkọ rẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, lẹyin to padanu anfaani lati ṣoju ẹgbẹ APC gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ.
Ninu ọrọ to kọ sori Instagraamu rẹ nipa ọkọ rẹ, Dọlapọ ni, ‘‘Oluleke, Ọmọluabi, Ọmọ ọkọ, Oninuure, Oniwapẹlẹ, Oniwatutu, Ọlọgbọn, Olododo Alaaanu, Iwuri nla lo jẹ fun mi!’’
Gbogbo awọn eeyan to ka ọrọ ti Dọlapọ kọ yii lo ti n ki i, ti wọn si n bu ọla fun un pe ọrọ gidi lo sọ, wọn ni aya rere lọọdẹ ọkọ ni. Bẹẹ ni wọn n kan saara si i pe obinrin rere ni fun atilẹyin nla to ṣe fun ọkọ rẹ. Bẹẹ lawọn eeyan si n bu ọla, ti wọn n sọrọ daadaa nipa Ọṣinbajo pe akikanju ọkunrin ni, akikanju ati ọmọluabi ni pẹlu.