Adewale Adeoye
‘‘Fun odidi ọdun mẹjọ gbako ti olori orileede yii tẹlẹ, Ajagun-fẹyinti, Muhammadu Buhari, fi wa nipo iṣakooso orileede yii ni ko fi ko ọrọ kankan jọ rara, owo rẹ ko le si i ninu akanti kan ṣoṣo to n lọ nipinlẹ Kaduna, bẹẹ ni ohun ọsin rẹ ko le rara, dipo ki ẹran ọsin rẹ maa le si i gẹgẹ bii erongba awọn eeyan kọọkan, ṣe lo tun n din si i, paapaa ju lọ, nigba to n fun awọn araalu kọọkan lara awọn ẹran rẹ. Ẹri ohun ti mo n sọ yii wa ninu fọọmu kan bayii ti Buhari fun ajọ kan to n ri si dukia tawọn oṣiṣẹ ijọba ilẹ yii ni ṣaaju akoko ki wọn to gba iṣẹ ijọba ati lẹyin ti wọn ba kuro lẹnu iṣẹ ijọba’’.
O ni akọsilẹ nipa dukia Buhari ko le rara, bẹẹ ni ko din, eyi atawọn ohun mi-in ni ma a fi sọ pe, olori bii Buhari ṣọwọn lawujọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ gbogbo.’ Eyi lọrọ to n jade lẹnu Alukoro eto iroyin fun aarẹ ana, Sheu Garba, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Garba Sheu ni ohun tawọn eeyan ko mọ pọ ju ohun ti wọn mọ lọ ninu igbesi aye Buhari. O ni Buhari ki i ṣe olori to n fi igba gbogbo ko dukia jọ rara, ko ya owo ele kankan ni banki nilẹ yii tabi loke okun, ko lowo loke okun rara, bẹẹ ni akanti kan ṣoṣo to n lo pẹlu ‘Union Bank’ nilẹ yii lo ṣi n lo titi digba yii, ẹri ọrọ ti mo n sọ foju han kedere nigba ti Buhari fi fọọmu awọn dukia rẹ silẹ fun ajọ kan to n ri si dukia awọn to fẹẹ gbaṣẹ ijọba nilẹ yii, eyi ti wọn n pe ni ‘Code Of Conduct Bureau’ (CCB). Fọomu rẹ fi han gbangba pe owo rẹ ko le rara ni banki kan to n lo nilẹ wa.
Bẹẹ o ba gbagbe, ofin ti kan an nipa fun gbogbo awọn oloṣelu ilẹ wa pata pe ki wọn maa ṣe afihan dukia ti wọn ba ni ko too di pe wọn gbaṣẹ ijọba ati lẹyin ti wọn ba fẹẹ fipo wọn silẹ fun ajọ kan bayii ti wọn n pe ni‘Code Of Conduct Bureau’ (CCB).
Dukia ti wọn ati ti iyawo wọn ni wọn gbọdọ ṣafihan rẹ fun ajọ naa. Bakan naa ni tawọn ọmọ wọn ti ọjọ ori wọn ba ti kọja ọmọọdun mejidinlogun.