Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, araalu to n lọ bii ogun niye, ni wọn ti ha ṣakolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lori ẹsun pe wọn lọọ ji dukia ijọba ko ni Kwara Hotel, to wa lagbegbe G.R.A, niluu Ilọrin, lasiko ti wọn ṣi ilẹkun otẹẹli naa kalẹ fun awọn ti ijọba fẹẹ lu dukia naa ni gbanjo fun.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju nijọba Kwara ti kede pe awọn ti n lu gbogbo dukia otẹẹli naa ni gbanjo faraalu latari pe wọn n ṣe atunṣe otẹẹli naa lọwọ, ti wọn si ni awọn yoo ra dukia tuntun rọpo, ṣugbọn lasiko ti eto lilu ni gbanjo yii n lọ lọwọ lawọn janduku kan ya wọ otẹẹli naa, ti wọn si n ji oniruuru dukia ko sa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni lọjọ kẹta ti ijọba bẹrẹ lilu awọn dukia ọhun ni gbanjo lọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ to kọja yii, lawọn janduku naa ya wọ otẹẹli naa, ti wọn si n ji awọn dukia gbe sa lọ.
Ejirẹ ni, titi di asiko yii ni awọn ṣi n ko awọn janduku naa ati pe awọn tọwọ ti tẹ yoo ti to ogun niye.
O tẹsiwaju pe afẹfẹ taju-taju ni awọn ọlọpaa tu da silẹ ki gbogbo awọn janduku naa too fọnka lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.
Aworan Kwara Hotel atawọn to lọọ ji dukia ijọba ko ree