Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọja olowo iyebiye lo ṣofo sinu ile alaja mẹta kan to wo lulẹ ni ikorita ti wọn n pe ni Adabor, laduugbo Aṣọ si Bodija, n’Ibadan.
Gẹgẹ bawọn olugbe adugbo naa to wa nile lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye ṣe sọ, wọn ni o pẹ ti ile naa ti n san, ṣugbọn ti ko ṣẹni to kọ ibi ara si i.
Ṣugbọn lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nile ọhun to jẹ ileetaja oogun oyinbo, ti wọn tun n lo aja kan ninu ẹ fun ṣọọṣi deede wo lulẹ nigba ti ẹnikẹni ko fura.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ku, tabi fara pa ninu iṣẹlẹ yii, apa miliọnu owo Naira kekere ko ka oogun atawọn ọja mi-in to wa nileetaja oogun naa, ti gbogbo wọn si poora sabẹ ogiri alapa.
Olugbe adugbo ọhun kan ṣalaye pe “Itẹ oku lo wa nibi ti wọn kọ ile yẹn si tẹlẹ, lasiko ijọba Gomina Akala ni wọn kọ ile yẹn sibẹ lẹyin ti wọn hu gbogbo oku to wa ni mọṣuari yẹn kuro, ti wọn si ta ilẹ yẹn fun ẹni to kọ ile yẹn.
“Ile yẹn ti di ẹgẹrẹmiti, o ṣe diẹ to ti n sọko, ko too di pe o wo lulẹ laajin ọjọ Sannde”.
Eto lati ko awọn ẹru to ha sabẹ oguluntu ile to wo lulẹ yii la gbọ pe wọn n gbiyanju lati ko lọwọ lasiko ti a n kọ iroyin yii.