Stephen Ajagbe, Ilorin
Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara ati ibudo idibo to sun mọ le ẹgbẹrun meji (1,872), ni eto iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ APC yoo ti waye, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Alaga APC ni Kwara, Alhaji Abdullahi Samari, lo sọ eleyii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, niluu Ilọrin. O ni gbogbo eto lo ti to lati ri i pe eto naa kẹsẹ jari.
O ni awọn alaamojuto yoo wa nikalẹ lati ri i pe nnkan lọ deede. O ṣekilọ pe awọn to ba fẹẹ da wahala silẹ ati da eto naa ru yoo da ara wọn lẹbi.
Samari tun ke si awọn agbofinro lati ṣewadii awọn to n da rogbodiyan silẹ lẹgbẹ APC, ki wọn si fi wọn jofin.
Bakan naa lo ni eto iforukọsilẹ yii wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ to laṣẹ lati dibo, ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun kejidinlogun. O ni ẹni ti ọjọ ori rẹ ko ba to bẹẹ ko gbọdọ de ibudo idibo naa.
O fi kun un pe ẹgbẹ yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lori awọn to ba n ṣe ohun to ta ko ofin ẹgbẹ naa, ṣugbọn ko si ootọ ninu ọrọ kan to n lọ pe wọn le awọn kan kuro lẹgbẹ.
Nigba to n dahun ibeere lori aṣẹ ile-ẹjọ kan to fofin de ẹgbẹ APC lati maa ṣeto iforukọsilẹ naa, o ni gẹgẹ bii alaga APC ni Kwara, oun ko gba iwe ile-ẹjọ, fun idi eyi, eto naa yoo tẹsiwaju.
O rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati lọ sibudo idibo wọn pẹlu aworan pelebe meji fun eto naa.