Ẹrọ to n gbe wọn goke ni Cocoa House ja lulẹ n’Ibadan, eeyan kan ku, awọn mẹta ṣeṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo oṣiṣẹ awọn ileeṣẹ to wa nile alaja mẹẹẹdọgbọn ti wọn n pe ni Cocoa House, n’Ibadan, atawọn onibaara wọn to wa wọn wa laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ni wọn sa asala fun ẹmi wọn nigba ti ẹrọ to n gbe wọn goke ja lojiji, to pa ọkan ninu awọn to n tun un ṣe, to si ṣe awọn mẹta mi-in leṣe rẹkẹrẹkẹ.

Ẹrọ ògùnsọ̀ tawọn oloyinbo n pe ni ẹlifétọ̀ yii la gbọ pe o bajẹ, ṣugbọn ti awọn to n tun un ṣe n ṣe e lọwọ lati bii ọjọ mẹta kan ko too ja lu awọn eeyan ni nnkan bii aago mọkanla aarọ Ọjọruu, Wẹsidee.

Cocoa House, eyi ti ijọba ẹkun Iwọ-Oorun Naijiria (ilẹ Yoruba) kọ lọdun 1965, nileeṣẹ Odua Investment Limited to jẹ ajumọni laarin awọn ijọba ipinlẹ ilẹ Yoruba n mojuto.

Oludari ẹka iroyin fun ileeṣẹ Odua, Ọgbẹni Victor Aitoro, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni “Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati tu ẹrọ to wa nibẹ tẹlẹ to ti gbó kuro, ki wọn gbe tuntun si i lo ti já sinu koto to wa lẹgbẹẹ ileeṣẹ yii. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ọkan ninu awọn ẹnjinnia to n ṣiṣẹ yẹn padanu ẹmi ẹ sinu ijanba yẹn.

“Mẹta ninu awọn ẹnjinnia yii tun fara pa, ṣugbọn ifarapa yẹn ko pọ lọ titi, a si ti gbe wọn lọ sileewosan fun itọju.

 

“A ti fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa atawọn alakooso ileeṣẹ to gba iṣẹ atunṣe kinni yẹn leti. Awọn ọlọpaa ti wa sibi, wọn ti ṣe gbogbo ojuṣe to yẹ ki wọn ṣe.”

Leave a Reply