Ẹṣọ Amọtẹkun fi panpẹ ofin gbe awọn Fulani darandaran mẹta pẹlu ogoji maaluu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn Fulani darandaran mẹta pẹlu maaluu wọn bii ogoji ni wọn n gbatẹgun lọwọ ninu ahamọ ẹsọ Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ Ondo lori ọkan-o-ọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Awọn darandaran ọhun lọwọ tẹ lẹyin ti wọn ti fi ẹran wọn ba ire oko awọn agbẹ kan jẹ lagbegbe Owode, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin, oludari ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni bii igba mẹta ọtọọtọ lawọn ti ṣe akanṣe idanilẹkọọ fawọn Fulani agbegbe ọhun lori ọna ti wọn le fi ṣe okoowo ẹran ọṣin wọn lai fi tiwọn pa ẹlomiiran lara, tabi ki wọn fi ba iṣẹ oniṣẹ jẹ.

O ni kayeefi lo jẹ fawọn nigba ti awọn gba ipe pajawiri lati ọdọ awọn agbẹ pe awọn darandaran ọhun tun ti bẹrẹ iwa baṣejẹ wọn.

O ni idi ree ti awọn fi gbera loju-ẹsẹ, ti awọn si mu ọna ibẹ pọn ti awọn si ri mẹta ninu awọn afurasi ọdaran naa mu pẹlu ọgọọrọ maaluu ti wọn da wọnu oko oloko.

Adelẹyẹ ni ẹsọ Amọtẹkun ṣẹṣẹ bẹrẹ eto kan ti wọn pe ni ‘Ṣiṣe afihan ipa’.

Eto yii lo ni awọn ṣe agbekalẹ rẹ lati gbogun ti ọpọlọpọ iwa ọdaran to saaba maa n waye lawọn oṣu ba, ba, ba to n pari ọdun.

O gba awọn araalu nimọran lati fọkan ara wọn balẹ, ki wọn si maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ nitori pe igbesẹ ti wọn ṣe ifilọlẹ naa ko wa fun didẹruba wọn.

 

Leave a Reply