Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ni awọn ti paṣẹ fawọn ẹsọ Amọtẹkun ni gbogbo awọn ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa nilẹ Yoruba lati bẹrẹ si i ṣiṣẹ pọ lori ati gbogun ti ipenija eto aabo to n koju awọn eeyan ẹkun naa lọwọlọwọ.
Alaga fun apapọ ẹgbẹ awọn gomina lẹkun Guusu Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii sọrọ yii lasiko to n fẹdun ọkan rẹ han lori ọpọlọpọ ẹmi ati dukia to ṣofo ninu akọlu tawọn agbebọn kan ṣe siluu Igangan, Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, loru ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Aketi funra rẹ fi sita lorukọ awọn gomina ẹkun Guusu Iwọ-Oorun yooku lo ti juwe iṣẹlẹ naa bii iwa ọdaju, ojo ati ika, eyi to ni gbogbo aye gbọdọ fọwọsowọpọ ki wọn doju ija kọ.
O ni loootọ lawọn ti ba awọn agbofinro sọrọ lati tete bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si wa gbogbo ọna tọwọ yoo fi tẹ awọn janduku ọhun ki wọn le fi wọn jofin, sibẹ, o ni awọn ti pasẹ fun awọn adari ẹsọ Amọtẹkun to wa lawọn ipinlẹ Yoruba mẹfẹẹfa lati pe ipade pajawiri, nibi ti wọn yoo ti fẹnu ko lori bi wọn ṣe fẹẹ maa ṣiṣẹ pọ lati pese aabo fawọn eeyan ẹkun naa.
Arakunrin ni ohun to da awọn loju ni pe awọn ẹni ibi kan ni wọn n ṣagbatẹru iwa ipaniyan ati janduku to n waye lawọn apa ibi kan lorilẹ-ede yii nitori ifẹ inu ara wọn.
O ni asiko ti to fun gbogbo awọn olufẹ alaafia lati fọwọsowọpọ, ki wọn si jumọ sọ ete ati imọ awọn ọbayejẹ naa dasan.
Arakunrin ni ni ti awọn ti awọn jẹ gomina to n ṣejọba lẹkun Guusu Iwọ-Oorun Naijiria, awọn ti pinnu ati duro lori ẹsẹ awọn, bẹẹ lawọn ṣetan ati ja fitafita fun aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ti awọn n dari.