Ẹṣọ oju popo lu alaboyun titi toyun fi walẹ lara ẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn oṣiṣẹ ẹsọ oju popo kan, Aboluja ati Ọlamigoke, ni wọn lu lalubami niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lori ẹsun pe wọn fiya jẹ obinrin arinrin-ajo kan titi toyun fi ja bọ lara rẹ.

Ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ naa to sọ fun ALAROYE ṣalaye pe alaboyun ọhun atawọn arinrin-ajo kan ni wọn jọ wa ninu ọkọ akero to n gbe wọn bọ lati Ikeji-Arakeji, lọ si Ọgbẹsẹ, n’ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ.

Awakọ yii ni wọn da duro nibi ti wọn ti n ṣayẹwo ọkọ loju ọna marosẹ Ileṣa si Ọwọ, ṣugbọn to kọ lati duro loju-ẹsẹ latari ọkọ ajagbe meji ti wọn n sare bọ niwaju.

Eyi lo bi awọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo naa ninu ti wọn fi doju ija kọ ọkunrin naa lẹyin to duro tan, ṣe ni wọn fipa wọ ọ jade ninu ọkọ, ti wọn si n po ẹkọ iya fun un mu.

Awọn ero inu ọkọ naa la gbọ pe wọn gbiyanju lati da sọrọ naa pẹlu alaye ti wọn ṣe fun wọn pe aabo ẹmi awọn ti awakọ naa n du ni ko fi duro nigba ti wọn kọkọ da a duro, ṣugbọn ẹyin eti wọn ni gbogbo alaye ọhun n bọ si.

Asiko ti wọn n fa ọrọ yii mọ ara wọn lọwọ ni wọn ni ọkan ninu awọn ẹṣọ oju popo ọhun ti obinrin alaboyun naa ṣubu lori iduro to wa, loju kan naa ni wọn lẹjẹ ti bẹrẹ si i da lara rẹ ko too di p’awọn eeyan kan sare gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, ti wọn si ni oyun to wa lara rẹ ti bajẹ.

Pẹlu ibinu lawọn ọlọkada kan fi ṣuru bo ẹṣọ oju popo naa, ti wọn si lu u bii aṣọ ofi, ko too di pe awọn ọlọpaa de sibẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹle ọhun, Alukoro fun ẹsọ ojupopo nipinlẹ Ondo, Abilekọ Olujayeọla, ni ahesọ patapata ni pe awọn oṣiṣẹ awọn lu alaboyun titi ti oyun fi bajẹ mọ ọn lara.

O ni loootọ ni awakọ naa kọ lati duro nigba ti wọn kọkọ da a duro, awọn oṣiṣẹ mi-in to wa niwaju lo ni wọn pada da a duro, ti wọn ko si jẹ ko raaye sa lọ.

Olujayeọla ni ori lo ko Aboluja yọ lọwọ awakọ naa pẹlu bo ṣe gbiyanju ati fi ọkọ tẹ ẹ pa nibi to ti n tiraka ati da a duro, O ni ko si alaboyun ti wọn ti subu debi ti oyun n bajẹ lara rẹ.

Alukoro ọhun ni ori lo ko ọkan ninu awọn oṣiṣẹ awọn, iyẹn Ọlamigoke, yọ lọwọ iku ojiji lọjọ naa latari akọlu tawọn eeyan kan ṣe si i, ti wọn si ṣe e leṣe kawọn agbofinro too de.

O ni oun loun sare pe awọn ọlọpaa nigba tọrọ ọhun ti fẹẹ yiwọ, ti wọn si waa gbe awakọ ati ọkọ rẹ lọ si tesan wọn.

Leave a Reply