Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ninu ọdun 2021 yii, meji ninu awọn iyawo Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, ni wọn kọ ọ silẹ, ti wọn sa kuro laafin, iyẹn lẹyin ti Olori Ọla ti kọkọ lọ loṣu kọkanla, ọdun 2020.
Awọn meji to kuro laafin ninu ọdun yii ni Olori Aanu ati Olori Damilọla. Ninu awọn mẹta naa, ọkan ninu wọn torukọ ẹ n jẹ Damilọla, to kuro laafin loṣu mẹfa sẹyin lo ti n bẹ awọn abiyamọ aye ati gbogbo eeyan pata bayii pe ki wọn ba oun bẹ Alaafin pada, nitori oju oun ti ja a wayi, oun ti ṣetan lati pada saafin gẹgẹ bii ayaba.
Ọjọ Aiku ọsẹ yii ti i ṣe Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ni Damilọla to bimọ ọkunrin kan fun Alaafin Ọyọ, bọ soju opo Instagraamu rẹ, nibi to ti kọkọ kede pe ọkọ oun ko tọju oun, ko tọju ọmọ, o tun fun ọrẹ oun loyun, ṣugbọn ọrọ ti yipada bayii pẹlu bo ṣe tun kọ ọ sibẹ bayii pe kawọn eeyan waa ba oun bẹ Iku Baba Yeye o. O ni oun ti ko ọrọ oun akọkọ jẹ bayii, oun fẹẹ pada saafin.
Bayii ni Dammy ṣalaye ara ẹ soju opo naa “Mo fẹẹ fi oju opo yii bẹbẹ fun aforiji lọwọ gbogbo ẹbi Adeyẹmi Alaafin Ọyọ, nipa ohun ti mo ti kọkọ sọ nipa wọn. Ẹ jọwọ, mo fẹ ki gbogbo yin mọ pe ki i ṣe pe ẹnikẹni fipa mu mi lati kọ ohun ti mo gbe jade yii, ori mi pe, mo mọ ohun ti mo n ṣe.
“Gbogbo ohun ti mo sọ tẹlẹ pe Alaafin ko tọju mi yẹn, irọ ni. Gbogbo ohun ti mo sọ nipa wọn laburu, irọ ni. Awọn ọrẹ lo ti mi, gbogbo ẹ dẹ su mi ni mo ṣe jade laafin. Ṣugbọn ni bayii, o ti han si mi kedere, mo si fi tọkan-tọkan tọrọ aforiji pẹlu bi mo ṣe gbiyanju lati fi ori ade wọlẹ ni gbangba.
“Mo ti lọ s’Ekoo ati Abuja lati bẹbẹ fun aforiji idile ọba, mo n kọ ọrọ yii pẹlu omije loju mi, mo si n bẹ gbogbo abiyamọ aye daadaa pe kẹ ẹ jọọ, kẹ ẹ ba mi bẹ ọkọ mi, Alaafin Ọyọ, pe ki wọn dariji mi, ki wọn jẹ ki n pada saafin.
“Gbogbo ẹyin ti mo si gbowo lọwọ yin, ma a da owo yin pada lẹsẹkẹsẹ ti mo ba ti pada sọdọ ọkọ mi laafin Ọyọ.”
Obinrin to fẹẹ pada sile ọkọ lẹẹkeji yii pari ọrọ rẹ pe oloye lọrọ oun le ye, ṣugbọn ohun to daju ni pe ko sibi to da bii ile ẹni.
Nigba ti Olori Damilọla kuro laafin, baba kan to ni oun loun ṣẹku foun gẹgẹ bii baba, parọwa sọmọbinrin naa pe ko pada sile ọkọ rẹ, ko yee parọ ohun ti Alaafin ko ṣe mọ ọn.
Baba naa sọ nigba naa pe bi Alaafin ṣe n tọju Dammy lo n tọju iya rẹ, bẹẹ naa lo si n tọju awọn aburo Damilọla, to n sanwo ileewe wọn bo ṣe yẹ. Ṣugbọn Damilọla bu baba naa lori afẹfẹ nigba naa, o ni were alatẹnujẹ ni.
Ayaba yii sọ pe baba naa ti lọọ gba abẹtẹlẹ lọwọ Alaafin lo ṣe n sọ isọkusọ lori afẹfẹ, o ni nibo ni baba yii wa nigba toun gba sọọbu fun mama oun, toun ko ọja sibẹ, toun n da sanwo ileewe ọmọ oun, to fi wa n gbeja Alaafin.
Afi bo ṣe tun waa di asiko yii ti Damilọla tun yi ilu pada, to tun ni Aafin Ọyọ ni Ọlọrun wa, ibẹ lo wu oun lati pada si, ki wọn ba oun bẹ ọkọ oun.
Ni ti Olori Aanu toun naa kuro laafin lọdun yii, ọsẹ to kọja yii lo ni oun n mu ọkunrin mi-in bọ wa sile, toun yoo fi ṣọkọ tuntun. Wọn si ni Olori Ọla to ṣide kikẹru jade laafin naa n jaye ori ẹ kiri Eko.