Monisọla Saka
Honey Berry, obinrin ẹleekeji to bimọ fun gbajumọ ọkunrin olorin taka-sufee tawọn ọdọ fẹran daadaa nni, Habeeb Okikiọla Ọmọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazu Zeh, ti kigbe le e lori lori ẹrọ ayelujara lati waa ṣe ẹtọ lori ọmọ toun bi fun un.
Portable ti awọn obinrin bii marun-un ọtọọtọ ti bimọ fun bayii, ni obinrin to n jẹ Honey Berry, ti Zaazu funra ẹ ti fẹsun kan nigba kan ri pe o n fi ọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu gba ikanni ayelujara Instagram lọ, lati ṣe fidio ko le ṣalaye gbogbo nnkan to ti n foju wi tẹni kan o mọ.
O ni abimọ ma tọ ni Portable, ati pe oju aye lasan ni bujẹ-budanu to maa n ṣe.
O ni, “Ẹ ba mi sọ fun Portable ko waa maa ṣe ojuṣe rẹ lori ọmọ ẹ o. Abi ṣe ọkunrin ọlọkunrin lo fẹ ko maa gbọ bukaata lori ọmọ ti mo bi fun un ni.
Oṣu kẹrin ree to ti ranṣẹ si wa kẹyin. Ariwo pe oun gba ile fun mi lo n pa kiri. Ile wo naa si ni, ile kan bayii to gba fun awọn to n ko kiri nigba naa ni. Nigba to ya ni mo ko sile oni abẹsitọọsi (asbestos) ọhun. Ṣe ile oni POP abi awọn ile ringindin igbalode tawọn ẹgbẹ ẹ n gba fobinrin lo gbe mi si ni.
“Ti n ba royin nnkan toju mi ri ninu oyun. Ilukuku bii ẹni lu bara lo maa n fi mi ṣe lai wo ti ipo ti mo wa. Koda ni gbogbo igba ti mo n damira, Portable ṣi n na mi.
Bẹẹ ki i ṣe pe mo fẹẹ ba ile wọn jẹ tabi pe mo bẹ mọ ọn, o loun ko niyawo nile ni mo ṣe gba fun un o.
Emi atiyawo to wa nile ẹ naa ṣaa wa ọna lati yanju aarin ara wa, a si tibẹ di ọrẹ, ṣugbọn ko dun mọ Portable ninu.
O ni mo n ba awọn eeyan kan sọrọ lori foonu yẹn.
Ti ki i baa ṣe pe o kuku ti gba foonu yẹn lọ lọwọ mi ni, awọn ẹri pọ nibẹ gidi gan-an ni. Amọ iyẹn ti lọ.
“Nitori pe emi ati iyawo to wa nile ẹ bayii, iyẹn Ọmọbẹwaji, tun jọ n ṣe ọrẹ, lilu lo maa n lu iyẹn naa bii ẹni lu bẹmbẹ. Yatọ siyẹn gan-an, iya, igbaju-igbamu lo fi maa n ji iyẹn laraarọ. Bẹẹ ni ko fẹ ka ni nnkan an ṣe papọ.
Ki Portable ma tọ mi o, o n gba lori mi gidi gan-an ni. Abi ko fẹẹ daa fun un ni. O tun waa ṣe fidio ti yoo fawọn eeyan lanfaani lati maa wo o bo ṣe n sọrọ lọwọ, o bẹrẹ si i pe mi ni oloṣo nibẹ.
“Emi dakẹ lati ọjọ yii wa nitori pe mo gbọn ju u lọ ni. Gbogbo bo ṣe n ba mi jẹ lori ẹrọ ayelujara ti mi o sọrọ, emi naa ko fẹẹ maa kéwe ni o. Gbogbo orukọ buruku to n pe mi ti mi o fesi, ki i ṣe ti ẹru ija, amọ nitori pe mi o fẹ ka ko ara wa sita ni. Tori kinni naa mọ ọn lara debii pe gbogbo nnkan to ba n ṣẹlẹ ninu igbesi aye ẹ lo maa n gbe saye fawọn eeyan. Oju aye oṣi lasan naa dẹ ni. Emi mọ pe ko gbọn, emi naa ko si fẹẹ maa huwa agọ to n hu nigba naa ni mi o ṣe fun un lesi.
Nitori eyi ni mo ṣe n bọ sita kawọn eeyan maa wo mi bi mo ṣe n sọrọ o’’.
Honey Berry ni nigba toun ti ri i pe akoṣibero ni loun ṣe tete ja ara oun gba, ti oun tẹpa mọṣẹ lati tọju ọmọkunrin toun bi fun un. O ni nitori igbiyanju oun yii lo ṣe n sọ pe alaṣẹwo loun, ṣugbọn toun n pariwo nisinyii pe ko waa ṣe baba ọmọ fọmọ ẹ nitori ti awọn eeyan ba n ṣaanu oun tabi ti ọkunrin kan ba n tọju oun, ko yẹ ki wọn tun maa ba a bọ ọmọ ẹ pẹlu gbogbo ẹnu to maa n ṣe.
O ni to ba jẹ pe o le ni in lara lati mu owo, ounjẹ, aṣọ atawọn nnkan mi-in wa fawọn, ko gbe e ran eeyan si awọn.
Ninu ọkan ninu itakurọsọ obinrin yii ati baba ọmọ ẹ ti wọn tun n pe ni idaamu adugbo, o ran Portable leti pe o ti le loṣu mẹrin to ti ranṣẹ si ọmọ ẹ, amọ ti Portable fun un lesi pe ko gbe ọmọ oun wa foun.
Honey Berry naa duro lori pe oun ko le fi ọmọ oun silẹ, nitori ko sẹni to mọ ọn wo bii ọlọmọ.
Tẹ o ba gbagbe, obinrin yii ni ẹni keji to bimọ fun Portable ti wọn tun n pe ni bukata ijọba apapọ, lẹyin Ọmọbẹwaji ti i ṣe iyawo ile ẹ. Amọ to tun jẹ obinrin ẹlẹẹkẹta ti yoo bimọ fun Ika gbogbo Afrika, ti wọn ba ka iyawo to kọkọ fẹ laaarọ ọjọ ẹ, amọ to ti ko si nile ẹ bayii mọ ọn.
Ọdun to kọja lo bimọ ọkunrin fun Portable, ikomọ to larinrin ni wọn si ṣe fọmọ naa.