Orin ọpẹ ati ijo ayọ lawọn ti wọn n gbe ni ojule kẹrinlelogun, Ọna Salvation, ni ilu Ọpẹbi lagbegbe Ikẹja fi n dupẹ, nigba ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ti ọkọ-ofurufu kekere (hẹlikoputa) ti ja saarin ile wọn lanaa yii. “Ẹ sa maa ba wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ki i ṣe inu ile gan-an lẹronmpileeni yii ja si, tabi ko jẹ oru ni, ohun ti yoo ṣẹlẹ yoo le ju bayii lọ!” Ẹni kan ninu awọn olugbe ile naa lo sọ bẹẹ.
Arabinrin Grace Awolaja sọ nibẹ pe awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko sẹni kan to ku ninu ile awọn, bo tilẹ jẹ pe awọn gbọ iku awọn ti wọn wa ninu baaluu naa, bẹẹ lo si sọ pe o yẹ ki awọn ẹlẹronpileeni wọnyi maa tun ọkọ wọn ṣe daadaa ki wọn too gbe wọn si oju ofurufu. O ni fun ọpọ iṣẹju ni baaluu naa fi n ra baba loju ọrun ko too di pe o ṣẹṣẹ waa ja lulẹ. Alaaji Saliu Bamidele tilẹ ni o le jẹ injinni ọkọ-ofurufu naa lo daṣẹ silẹ, nitori bo ṣe ja lojiji bẹẹ ya awọn paapaa lẹnu.
Niṣe ni hẹlikoputa naa fa ara ogiri ile to ja bọ si ya, to si ba mọto to wa nibẹ jẹ pata. Mark Okeke to ni ṣọọbu aṣọ tita lọọọkan iwaju ile naa sọ pe awọn ti ri ẹronmpileeni naa to n pooyi loju ọrun, to si n fẹẹ ja bọ sinu ọ̀gbun kànáà to wa nitosi ibẹ, afi bo ṣe tun gbera paa lẹekan naa, lo ba doju kọ ile yii, ojiji lawọn si gbọ ariwo nla, ti eruku si bo gbogbo oju ọrun dáru. Okeke ni, “Ọpọ awọn ti wọn n gbe ile naa ni wọn ko si nile, Ọlọrun lo yọ wọn!”