Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn eeyan ilu Ifọn, nijọba ibilẹ Orolu, ti kilọ fun olori awọn ọmọ ologun lorileede Naijiria, Taoheed Lagbaja, lati ma ṣe da ogun silẹ laarin ilu naa ati ilu tiẹ, Ilobu.
Ọmọ bibi ilu Ilobu, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ni Lagbaja, ilu naa si wa nifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ilu Ifọn.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, gẹgẹ bi awọn eeyan ilu Ifọn ṣe wi, ni ọpọlọpọ awọn ọmọ ileeṣẹ ologun ya wọ ilu naa, ti wọn si n rin kaakiri awọn ilẹ to jẹ ti ilu Ifọn.
Gẹgẹ bi adele Olufọn, Oloye Agba Babatunde Oyetunji, ṣe wi, iwadii fi han pe ṣe ni ileeṣẹ ologun fẹẹ kọ ibudo kan sibẹ lai sọ fun awọn mọlẹbi to ni ilẹ naa, ati pe ọrọ ilẹ ti wọn n sọ yii wa nile-ẹjọ lọwọlọwọ.
Oyetunji ṣalaye pe bii igba ti Lagbaja fẹẹ fi ọwọ ọla gba awọn eeyan ilu Ifọn loju ni igbesẹ awọn, idi niyi ti awọn fi pariwo sita ki ọrọ naa too di wahala.
Ọkan lara awọn aṣoju awọn ọmọ bibi ilu Ifọn, Jide Akinyọoye, ṣalaye pe ilu Ifọn ko lodi si idagbasoke to ba fẹẹ wọ agbegbe naa, ṣugbọn Lagbaja gbọdọ tọ ọ lọna to tọ.
Akinyọoye ke si Aarẹ Bọla Tinubu ati Gomina Adémọ́lá Adeleke lati tete da si ọrọ naa, nitori ohunkohun ti ileeṣẹ ologun ba kọ si ori ilẹ Ifọn, wọn ko gbọdọ kọ orukọ Ilobu si i, orukọ Ifọn lo gbọdọ wa nibẹ.