Ẹ da mi pada sọdọ Boko-Haram ọkọ mi, mo nifẹẹ rẹ- Ọmọbinrin Chibok

Jamiu Abayọmi

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii, ni Ikọ ọmọ ologun ilẹ wa ti wọn pe ni 81 Battalion, tun ri ọkan lara awọn ọmọleewe Chibok tawọn ikọ agbesunmọmi alakatakiti Boko-Haram  ji gbe lọdun 2014, ti wọn porukọ rẹ ni Mary Nkeki, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn gba silẹ.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti ikọ awọn ọmọ-ologun ilẹ wa ya wọ ibuba awọn afẹmiṣofo yii ni wọn ri ọmọbinrin naa gba silẹ pẹlu ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, Adamu, to loun jọwọ ara oun silẹ.

Nigba ti Ọgagun Gold Chibuisi n fidi ọrọ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ yii, o ni ipo karundinlọgọta ni orukọ Nkeki wa lara awọn ọmọ-iwe ti wọn ji gbe naa.

“Lasiko to fi wa ni ahamọ awọn agbesunmọmi yii ni wọn ti fipa fun un lọkọ laarin wọn, ọkọ rẹ ọhun si ni ọmọkunrin Adamu ti a jọ ri gba silẹ lasiko ti a lọọ ka wọn mọ.

“Latigba to si ti wa nibi lo ti lọọ ṣe oriṣiiriṣii ayẹwo, ti o si ti n gbadun daadaa, a o ti i fa le ijọba ipinlẹ Borno lọwọ”.

Lẹyin ti ọmọbinrin naa dele ijọba ipinlẹ Borno, lẹka to n ri si ọrọ obinrin, lo ti ni oun ti lọkọ, ati pe Adamu ni ọkọ oun, oun si ti bimọ meji fun un, bo tilẹ jẹ pe wọn ti ku, ṣugbọn Adamu ni ki wọn fa oun fun gẹgẹ bii ọkọ.

“Emi ati Adamu ti fẹ ara wa, a si jọ sa kuro ki awọn ọmọ ologun too gba wa silẹ ni lẹyin to loun ko ṣe Boko-Haram mọ, oun ni mo si nifẹẹ lati fẹ pada”.

Latigba ti wọn ti gba awọn mejeeji silẹ ni wọn ti ya wọn sọtọ, ti Adamu wa nibi to ti n gba ilanilọyẹ ati idanilẹkọọ ti wọn maa n fun awọn ti wọn ba juwọ silẹ pe awọn ko ṣe igbesunmọmi ati jagidijagan mọ.

Ileeṣẹ ọmọ ologun ti fidii ẹ mulẹ pe ọwọ awọn n dẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, tawọn si n ri awọn ọmọbinrin ileewe Chibok gba silẹ diẹdiẹ. Koda, Mary Nkeki ni yoo jẹ ẹlẹẹkẹrindinlogun ti awọn yoo gba kalẹ laaarin oṣu perete sira wọn yii. Wọn tun waa ṣeleri pe awọn ko ni i dawọ igbiyanju duro titi tawọn yoo fi gba awọn to ku lahaamọ silẹ lọwọ awọn kọlọransi ẹda yii, tawọn ọmọ yii yoo si pada wale waa ba awọn mọlẹbi wọn layọ ati alaafia.

 

 

Leave a Reply