Ẹ faaye gba awọn ọmọ Naijiria to fẹẹ kawe pẹlu awọn ẹbi wọn – Ẹgbẹ akẹkọọ.

Monisọla Saka

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹ-ede Naijiria, National Association of Nigerian Students (NANS), ti ke si ijọba ilẹ United Kingdom, lati yi ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe pada, nitori nnkan to le da mọlẹbi ru ni. Ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn ti ni iru ofin bẹẹ ko tilẹ gbọdọ waye, depo pe yoo fẹsẹ mulẹ, nitori okunfa ipinya laarin lọkọlaya ni ofin ọhun.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, nijọba UK gbe ofin tuntun jade pe lati inu oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, awọn ko ni faaye gba awọn akẹkọọ lati ilẹ Naijiria atawọn orilẹ-ede mi-in niluu awọn lati ko awọn mọlẹbi wọn dani ti wọn ba fẹẹ kawe gboye imọ ijinlẹ keji, ayafi awọn ti wọn fẹẹ gboye Ọmọwe (PhD), nitori bi iyẹn ṣe maa n gba to ọdun mẹta si marun-un ki wọn too pari.

Ofin tuntun wọn yii waye latari bi wọn ṣe ni ero tawọn to fẹ waa kawe n ko lẹyin pọ ju awọn akẹkọọ funra wọn lọ. Ati pe eleyii ti n ṣakoba fun ilu awọn, nitori bawọn eeyan ṣe n fojoojumọ pọ si i. Nigba ti wọn si tun fọrọ wa ọkunrin ọmọ ilẹ Naijiria kan lọhun-un, Emdee Tiamiyu, lẹnu wo, to ti jẹ ko ye wọn pe ọna lati ribi sa kuro nilẹ Naijiria ni iwe ti wọn wa n ka ni wọn ṣe fibinu gbe ofin lile naa kalẹ.

Ninu atẹjade ti igbakeji Aarẹ ẹgbẹ NANS lori ọrọ ode, Akintẹyẹ Babatunde Afeez, buwọ lu ni wọn ti sọ pe, “Awọn akẹkọọ Naijiria bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn, ni wọn bẹrẹ eto ikẹkọọ saa ọdun 2021/2022 nikan nilẹ UK, odidi biliọnu Yuro (2 billion Euro), ni wọn si ri latara owo ileewe awọn ọmọ Naijiria nikan ṣoṣo.

‘‘Nnkan to wa n dun eeyan ju ninu ọrọ yii ni bi wọn ṣe fẹẹ yi eto ajọṣepọ laarin ololufẹ pada labẹ eto ẹkọ atawọn ti wọn fẹ lọ ṣiṣẹ nibẹ”.

Wọn tẹsiwaju pe ofin ma mu ọmọ, iyawo tabi ẹbi kankan lọwọ ko le tan iṣoro apọju ero ti wọn n wa ọna abayọ si niluu wọn, ati pe dipo bẹẹ, wọn yoo kan ko idaamu ọkan ba awọn ti wọn fẹ lọ kawe ni, nigba ti ọkan wọn ba ti pin yẹlẹyẹlẹ nitori awọn eeyan wọn ti ko si nibi ti wọn wa, eyi ti wọn ni o le mu ki ikuna de ba iru ẹni bẹẹ.

Nigba ti wọn n sọrọ lori ọna abayọ si ọrọ naa, wọn ni ki ijọba ilẹ UK ṣe ofin ti yoo mu ki aarin ẹbi duroore, ki i ṣe eyi ti yoo tu wọn ka, ki ajọṣepọ aarin ilẹ wọn atawọn ọmọ Naijiria to fẹẹ lọ kawe lọdọ wọn ma baa bajẹ.

Wọn sọ siwaju si i pe obitibiti owo lo n wọ apo ijọba wọn latara awọn ọmọ ilẹ mi-in to waa n kawe niluu wọn, ki wọn ro gbogbo eleyii, ki wọn si gba awọn eeyan laaye lati maa wa pẹlu mọlẹbi wọn.

Bakan naa ni wọn rọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere nilẹ Naijiria, ileeṣẹ to wa fawọn ọmọ Naijiria lẹyin odi, Nigerian in Diaspora Commis (NIDCOM), atawọn eekan mi-in pe ki wọn ba awọn ijọba UK sọrọ lati yi ofin to le da ẹbi ru ti wọn ṣe pada.

 

Leave a Reply