Faith Adebọla, Eko
Dokita Joe Okei-Odumakin, iyawo gbajugbaja ajafẹtọọ nni, Oloogbe Yinka Odumakin, ti bẹnu atẹ lu bawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ, DSS, ṣe lọọ ṣakọlu sile ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho laipẹ yii, o ni iwa aidaa gbaa lawọn agbofinro naa hu, ko si ba ẹtọ ijọba dẹmokiresi mu rara.
Ninu atẹjade kan to fi lede l’Ekoo, lọjọ Aje, Mọnde yii, ni Okei-Odumakin, to jẹ Aarẹ ẹgbẹ aladaani kan to n ṣe igbelarugẹ eto ijọba dẹmokiresi, Campaign for Democracy, ti beere pe kijọba ma ṣafira, ki wọn tete tu gbogbo awọn ti wọn mu nile Sunday Igboho silẹ, ki wọn si tọrọ aforiji fun iwa ta-ni-maa-mu-mi ti wọn hu ọhun.
O ni nnkan itiju niwa tawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ naa hu, ko si ba laakaye mu rara, o ni nnkan abuku ni forileede yii paapaa.
“Nigba kan, nigba ijọba ologun Sani Abacha, niṣe lawọn orileede agbaye to ku n wo Naijiria tika tẹgbin, bii ilu kan ti ko bẹgbẹ pe, ti ko si wuyi lawujọ, eyi si ṣakoba fawọn ọmọ orileede yii. Ko yẹ ka tun ba ara wa niru ipo abuku bẹẹ mọ, tori abẹ ijọba demokiresi la wa yii, ijọba awa-ara-wa tawọn eeyan kan ti fi ẹmi wọn, igbesi aye wọn ati okun wọn ja fitafita fun.
Abẹ ofin ati ẹtọ la wa, o si yẹ ka bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan, tori ofin ilẹ wa to funjọba laṣẹ naa lo fun araalu lawọn ẹtọ ati anfaani kan, ko si daa bijọba ṣe n lo ọwọ agbara ti ofin fun wọn lai bikita fun ẹtọ ọmọniyan araalu labẹ ofin kan naa.
Ṣiṣe iwọde ati ifẹhonu han jẹ apa pataki ninu iṣejọba awa-ara-wa, afi to ba jẹ ki i ṣe dẹmokiresi la sọ pe a n ṣe lo ku.
Bawọn agbofinro ṣe lọọ gbọn ile Oloye Sunday Igboho yẹbẹyẹbẹ, ti wọn si ṣe akọlu si i lai niwee aṣẹ yẹn, awọn ilu ti ko seto, ti ko nilana pato kan ni wọn ti n ṣe’ru ẹ.
Bi wọn ṣe lọọ ba dukia rẹpẹtẹ jẹ nile ẹni tile-ẹjọ ko ti i sọ boya o jare tabi jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ṣajeji si ilana iṣejọba demokiresi, ko si ba ilana ofin mu.”
Latari eyi, o ni oun ati ajọ toun n dari beere pe kijọba tete tu awọn ti wọn mu sahaamọ nibi iwọde Yoruba Nation l’Ọjọta, silẹ, ki wọn si bẹrẹ iwadii lori ọmọbinrin kan ti wọn lawọn ọlọpaa yinbọn pa nibi iwọde ọhun lọjọ Satide.
O ni dipo tijọba yoo fi maa dọdẹ Sunday Igboho kiri bii ẹni dọdẹ ekute, niṣe ni ki wọn gbaju mọ ọrọ awọn janduku agbebọn atawọn afẹmiṣofo to n ṣekupa awọn ọmọ Naijiria kaakiri, o ni ẹtọ ti Sunday Igboho ni labẹ ofin lo fun un lanfaani lati ṣewọde ta ko ijọba ti ko daa, wọn o si gbọdọ tẹ ẹtọ rẹ loju tabi dunkooko mọ ọn.