Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ orile-ede wa, ‘Department Of State Service’ (DSS) ti ṣekilọ gidi fun gbogbo awọn eeyan orile-ede Naijiria pe ki wọn maa rin pẹlu ifura ni gbogbo akoko ti ajọyọ ọdun Ileya ba n lọ lọwọ kaakiri origun mẹrẹẹrin orile-ede yii nitori pe awọn ti ri ẹri gidi pe o ṣee ṣe ki awọn janduku afẹmiṣofo tun ṣoṣẹ, to si le ja si iku fawọn araalu.
ALAROYE gbọ pe lara awọn ibi kọọkan tawọn ọlọpaa DSS ọhun sọ pe o ṣee ṣe ki awọn ọdaran naa ti ṣọṣẹ ni awọn ibi gbogbo tawọn eeyan maa n pọ si lakooko ọdun ileya atawọn ibi tawọn ẹlẹsin Musulumi ti maa n kirun Yidi, to fi mọ awọn ati ibi tawọn eeyan ti n ṣe faaji lasiko ayẹyẹ ‘Recreational Center’.
Alukoro awọn DSS, Ọgbẹni Peter Afunanya, ṣalaye pe pẹlu bawọn ṣe n fojoojumọ gba bọnbu lọwọ awọn ọdaran kọọkan tawọn n mu kaakiri laarin ilu ti fi han pe wọn ni iṣẹ aburu kan ti wọn fẹẹ ṣe lakooko ọdun Ileya to n bọ lọna yii.
O waa rọ gbogbo awọn araalu pata pe ki wọn ṣọra ṣe gidigidi lakooko ajọyọ ọdun Ileya to n bọ yii, ki wọn si yẹra nibi ti ọpọ ero ba pejọ si. Bakan naa lo rọ wọn lati tete f’ọrọ awọn ẹni ti irin rẹ ko ba mọ lagbegbe wọn to ọlọpaa leti, ki wọn le tete fọwọ ofin mu wọn.
Siwaju si i, Afunaya ni, “A n fi akoko yii rọ gbogbo awọn to maa wa nibi ile igbafẹ gbogbo pe ki wọn maa woye ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe wọn daadaa. Bakan naa ni kawọn to n ṣakooso awọn ọja igbalode gbogbo naa maa ṣakiyesi awọn ohun to n ṣẹlẹ layiika wọn.
“Awọn ohun ija oloro bọnbu ta a ri gba lọwọ awọn ọdaran kọọkan laipẹ yii fi han pe, o ṣee ṣe ki wọn kọ lu awọn araalu lakooko ọdun ileya to n bọ yii. Awa paapaa ko ni i tura silẹ rara lori ọrọ awọn ọdaran naa.