Aderounmu Kazeem
Ọkan lara ileeṣẹ agbofinro orilẹ ede yii, DSS, ti ke gbajare pe ki awọn eeyan ṣọra nitori awọn eeyan kan ti n gbero lati fi ọrọ ẹsin dá wahala silẹ lawọn ipinlẹ kan nilẹ Yorùbá.
Lara awọn ipinlẹ ti wọn sọ pe ikọlu ọhun yóò ti waye gẹgẹ bíi olobo to ta awọn ni ipinlẹ Eko, Ọyọ atawọn ibomi-in ni Naijiria.
Ohun tí àjọ DSS sọ ni pe niṣe lawọn eeyan buruku yii pẹlu ìfọwọ́sowọ́pọ̀ awọn ẹlẹgbẹ wọn láwọn orilẹ-ede kan fẹẹ máa fi ọrọ ẹsin da wahala silẹ, bẹẹ lawọn èèyàn gbọdọ sọra lori ohun to lè mú ikọlu wa nitori ọrọ ẹsin lagbegbe wọn.
Yatọ si ilẹ Yoruba awọn ipinlẹ mi-in ti wọn tun darukọ pe awọn eeyan yii ni gbero lati fi ọrọ ẹsin da nnkan ru ni ipinlẹ Rivers, Sokoto, Kano, Kaduna ati Plateau.
Agbẹnusọ fun ẹṣọ agbofinro DSS, Dokita Peter Afunanya, sọ pe èròngbà awọn eeyan yii ni lati da rukerudo silẹ nipa kikọlu awọn ile ijọsin atawọn aṣáájú lawọn ibi ìjọsìn ọhun.
Ninu atẹjade ọhun lo tun ti sọ pe, “Lara ohun ti awọn oniṣẹ ibi yii fẹẹ ṣe ni pe wọn fẹẹ da wahala silẹ laarin ẹsin, bẹẹ ni wọn tún fẹẹ lo awọn janduku ọmọ ẹgbẹ wọn lati máa fi kọlu awọn ile ijọsin, awọn aṣáájú ẹṣin, atawọn aaye pàtàkì kan láàrin ìlú.
“Fún ìdí èyí, a fẹẹ fi asiko yii rọ kaluku lati yẹra fún gbogbo nnkan to le di àlàáfíà ilu lọwọ, abi ohunkohun to le mu ẹni meji tabi ìjọ ẹsin kọlu ara wọn.”
Siwaju si i, ìkọ ẹṣọ agbofinro DSS yii ti ṣèlérí láti tubọ mu eto aabo le dan-in-dan-in pẹlu ìfọwọ́sowọ́pọ̀ awọn ìkọ ẹṣọ agbofinro yooku fún ètò ààbò tó péye.
Bakan naa ni wọn ti ke sí àwọn èèyàn orilẹ ede yii lati ma jẹ ki eti awọn ìkọ ẹṣọ agbofinro di ni kete ti wọn ba ti kẹẹfin ohunkohun to ba le di alaafia ilu lọwọ.